orílẹ̀-èdè olómìnira ní Ìwọ̀òrùn Áfríkà From Wikipedia, the free encyclopedia
Nàìjíríà (pípè /naɪˈdʒɪrɪə/) jẹ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira tí ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì tó fi mọ́ Agbẹ̀gbẹ̀ Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní apá Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Orílẹ̀-èdè yí pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Benin ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ó tún pààlà pẹ́lú orílẹ̀-èdè olómìnira ti Nijẹr ní apá àríwá, Chad àti Kamẹróòn ní apá ìlà Oòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni ó jẹ́ Olú-Ìlú fún orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ní ẹ̀yà púpọ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n hànde tí wọ́n tóbi jùlọ, tí wọ́n sì pọ̀ jùlo, tí a sì kó àwọn ẹ̀ka ìsọ̀rí ìsọ̀rí èyà tókù sí abẹ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni Ẹ̀ya Hausa, Ẹ̀ya Ìgbò ati Yorùbá.
Ṣíṣàtúnṣe àyọkà yìí látọwọ́ àwọn oníṣe tuntun tàbí àwọn oníṣe aláìtíìforúkọsílẹ̀ jẹ́ tí tìpa lọ́wọ́lọ́wọ́. See the protection policy and protection log for more details. If you cannot edit this àyọkà and you wish to make a change, you can submit an edit request, discuss changes on the talk page, request unprotection, log in, or create an account. |
Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà | |
---|---|
Motto: "Ìṣọ̀kan àti Ìgbàgbọ́, Àlàáfíà àti Ìlọsíwájú" | |
Olùìlú | Àbújá 9°4′N 7°29′E |
Ìlú tótóbijùlọ | Èkó 6°27′N 3°23′E |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | Gẹ̀ẹ́sì |
Àwọn èdè ọmọ orílẹ̀-èdè | |
Àwọn èdè míràn[1] | |
Orúkọ aráàlú | Ará Nàìjíríà |
Ìjọba | Orílẹ̀-èdè olómìnira olóòfin-ìbágbépọ̀ ààrẹ ìjọba àpapọ̀ |
• Ààrẹ | Bọ́lá Tinúbú |
Kashim Shettima | |
• Ààrẹ Ilé Alàgbà | Godswill Akpabio |
• Agbẹnusọ Ilé Aṣojú | Tajudeen Abbas |
Olùdájọ́ Olukayode Ariwoola | |
Aṣòfin | Iléìgbìmọ̀ Aṣòfin |
• Ilé Aṣòfin Àgbà | Ilé Alàgbà |
• Ilé Aṣòfin Kéreré | Ilé àwọn Aṣojú |
Òmìnira kúrò lọ́wọ́ Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan | |
• Ìsopọ̀ Apágúúsù àti Apáàríwá Náìjíríà | 1 January 1914 |
• Jẹ́ fífilọ́lẹ̀ àti dídálóhùn | 1 October 1960 |
• Ó di orílẹ̀-èdè olómìnira | 1 October 1963 |
• Òfin-ìbágbépọ̀ lọ́wọ́ | 29 May 1999 |
Ìtóbi | |
• Total | 923,769 km2 (356,669 sq mi) (32nd) |
• Omi (%) | 1.4 |
Alábùgbé | |
• 2020 estimate | 206,630,269[2] (7th) |
• 2006 census | 140,431,691 |
• Ìdìmọ́ra | 218/km2 (564.6/sq mi) (42nd) |
GDP (PPP) | 2020 estimate |
• Total | $1.275 trillion[3] (23rd) |
• Per capita | $6,232 (129th) |
GDP (nominal) | 2020 estimate |
• Total | $504.57 billion[3] (27th) |
• Per capita | $2,465 (137th) |
Gini (2020) | 35.1[4] medium |
HDI (2018) | ▲ 0.534[5] low · 158th |
Owóníná | Naira (₦) (NGN) |
Ibi àkókò | UTC+01:00 (WAT) |
Ojúọ̀nà ọkọ́ | ọ̀tún |
Àmì tẹlifóònù | +234 |
Internet TLD | .ng |
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ.[6] Agbegbe Benue-Cross River jẹ́ rírò gẹ́gẹ́ bí ile àkókó àwọn Bantu arókèrè ti wón fán káàkiri òpó ààrin àti apágúúsù Áfríkà bí irú omi ní ààrin ẹgbẹ̀rúndún akoko àti ẹgbẹ̀rúndún kejì.
Orúkọ Nàìjíríà wá láti Odò Ọya, tí a tún mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Odò Náíjà, èyí tó sàn gba Nàìjíríà kọjá. Flora Shaw, tí yíò jẹ́ ìyàwó lọ́jọ́ wájú fún Baron Lugard ará Britan tó jẹ́ alámójútó àmúsìn, ló sẹ̀dá orúkọ yìí ní òpin ọdún 1897.
Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè tó ní èèyàn púpò jùlọ ní Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ikejo ni agbaye[7], bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ní àwọn eniyan alawodudu jùlọ láyé. Ó wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tí a ń pè ní "Next Eleven" nítorí okòwò wọn, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú Ajoni àwọn Ibinibi. Okòwò ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èyí tó ń dàgbà kíákíá jùlọ lágbàáyé pẹ̀lú IMF tó ń gbèrò ìdàgbàsókè 9% fún 2008 àti 8.3% fún 2009.[8][9][10][11] Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 2000 sókè, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà gbé pẹ̀lú iye tó dín ní US$ 1.25 (PPP) lójúmọ́.[12] Nàìjíríà ní okòwò rẹ̀ tóbi jùlọ ní Áfíríkà, ati alágbára ní agbègbè Iwoorun Afirika.
Àwọn ará Nok ní ààrin Nàìjíríà se ẹ̀re gbígbẹ alámọ̀ tí àwọn onímọ̀ ayéejọ́un tí wárí.[13] Ère Nok tó wà ní Minneapolis Institute of Arts, júwè é ẹni pàtàkì kan mú "Ọ̀pá idaran" dání ní owó ọ̀tún àti igi ní owó òsì. Ìwònyì ní àmì-ìdámọ̀ aláse tó jẹ́ bíbásepọ̀ mò àwọn fáráò ilè Egypti ayéejọ́un àti òrìṣà, Oṣíriṣ, èyí lo n so pé irú àwùjọ, idimule, bóyá àti ẹ̀sìn ilè Egypti ayeijoun wà ní agbẹ̀gbẹ̀ ibi tí Nàìjíríà wà lónìí ní ìgbà àwọn Fáráò.[14]
Ní apá àríwá, Kano àti Katsina ní ìtàn Àkọsílè tí ọjọ́ wón dẹ́yìn tó bí ọdún 999 kJ. Àwọn ìlú-ọba Haúsá àti Ilé-ọba Kanem-Bornu gbòòrò gẹ́gẹ́ bí ibùdó ajẹ́ láàrin Àríwá àti Ìwọ̀ọòrùn Áfríkà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún 19sa lábé Usman dan Fodio àwọn ará Fúlàní di àwọn olórí Ilé-ọba Fúlàní lójúkan èyí tó dúró bayi títí di 1903 nígbàtí wọn jẹ́ pínpín láàrin àwọn àlámùúsìn ará Europe. Láàrin 1750 àti 1900, ìdá kan sí ìdá méjì nínú meta àwọn oníbùgbẹ́ àwọn ìlù Fúlàní jẹ́ eru nítorí ogun.[15]
Àwọn Yorùbá ka ọjọ́ tí wọ́n ti wà ní agbègbè Nàìjíríà, Benin àti Togo ayéòdeòní sẹ́yìn dé bí ọdún 8500 kJ. Àwọn Ìlú-ọba Ifẹ̀ àti Ọ̀yọ́ ní apá Ìwòòrùn Nàìjíríà gbalẹ̀ ní 700-900 àti 1400 ní sísẹntẹ̀lé. Síbẹ̀síbẹ̀, ìtàn àríso Yorùbá gbàgbọ́ pé Ilé-Ifẹ̀ ni orísun ẹ̀dá ènìyàn pe bẹ́ẹ̀ sì ni ó síwájú àsà-ọ̀làjú míìràn. Ifẹ̀ sẹ̀sọ́ ère alámọ̀ àti onítánganran, Ìlú-ọba Ọ̀yọ́ si fẹ̀ de ibi tí Togo wà loni. Ìlú-ọba míìràn tó tún gbalẹ̀ ní gúúsù apáìwòọ̀rùn Nàìjíríà ní Ìlú-ọba Benin láti ọ̀rúndún 15ru 19sa. Ìjọba wọn dé Ìlú Èkó kí àwọn ara Portugal ó tó wá sọ ibẹ̀ di "Lagos."[16]
Ní apá gúúsù ìlà-oòrùn Nàìjíríà, Ìlú-ọba Nri tí àwọn Igbo gbòòrò láàrin ọ̀rúndún 10wa títí de 1911. Eze Nri ni ó jọba Ìlú-ọba Nri. Ilu Nri jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́ bí ìpilèsè àsà ígbò. Nri àti Aguleri, níbi ti ìtàn àrísọ ìdá Igbo ti bẹ̀rẹ̀, wà ní agbẹ̀gbẹ̀ ìran Umueri, àwọn tí wọ́n sọ pé ìran àwọn dé ilẹ̀–ọba Eri fúnra rẹ̀.[17]
Àwọn Portuguese Empire ni wọ́n jẹ́ ará Europe àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ìsòwò ní Nàìjíríà tí wọ́n sì sọ èbúté Eko di Lagos tí wọ́n mú látara orúkọ ìlú Lagos ní Algarve. Orúkọ yìí lẹ̀ mọ́bẹ̀ bí àwọn ará Europe míìràn náà ṣe bẹ̀rẹ̀ síní sòwò níbẹ̀. Àwọn ará Europe ṣòwò pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà abínibí ní ẹ̀bá–odò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ owo eru níbẹ̀, èyí tó pa ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀yà abínibí Nàìjíríà lára. Lẹ́yìn tí ogun Napoleon bẹ̀rẹ̀, àwọn ará Britani fẹ ìsòwò dé àárín Nàìjíríà.
Ni 1885, ìgbẹ́sẹ̀lé Ìwọ̀oòrùn Áfríkà látọ́wọ́ àwọn ará Britain gba ìdámọ̀ káríayé. Nígbà tó sì di ọdún tó tẹ̀lé e, ilé-iṣẹ́ Royal Niger Company jẹ́ híháyà lábẹ́ Sir George Taubman Goldie. Ní 1900, àwọn ilẹ̀ tí ilé-iṣẹ́ yìí ní di ti ìjọba Britain.
Ni January 1901, Nàìjíríà di sísọ–di–ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi ìlànà àláàbò. Nàìjíríà sì di ara Ilẹ̀–ọbalúayé Britain tó wà lára alágbára nígbà náà.
Ní 1914, àgbègbè náà di sísọ-di-ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi Ìmúsìn àti Aláàbò ilẹ̀ Nàìjíríà (Colony and Protectorate of Nigeria). Fún àmójútó, Nàìjíríà di pínpín sí ìgbèríko apá-àríwá, apá-gúúsù àti Ìmúsìn Èkó. Okòwò ayé òde òní tẹ̀̀ síwájú ní wàrànsesà ní gúúsù ju ní àríwá lọ, ipa èyí hàn nínú ayé olóṣèlú Nàìjíríà òde òní. Ní ọdún 1936 ni òwò ẹrú ṣẹ̀ṣẹ̀ di fífòfin lù.[19]
Lẹ́yìn Ogun Agbaye Eleekeji gẹ́gẹ́ bíi èsì fún ìdàgbà isonibinibi Nàìjíríà àti bíbéèrè fún òmìnira, àwọn ìlànà–ìbágbépọ̀ tó rọ́pò ara wọn tí wọ́n jẹ́ sísọdòfin látowọ́ Ìjọba Britain mú Nàìjíríà súnmọ́ Ijoba-ara-ẹni tó dúró lórí aṣojú àti àpapọ̀. Nígbà tó fi di àárín ọ̀rúndún 20ji, ìjàgbara fún òmìnira jà káàkiri Áfríkà.
Ní ọjọ́ kìíní, oṣù Ọ̀wàrà, ọdún un 1960, Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ orílè-èdè Sisodokan Ilu-oba. Ilẹ̀ Olómìnira tuntun yìí mú kí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ orílè-èdè kí ẹ̀yà tiwọn ó jẹ́ èyí tó lágbára jù lọ. Ìsèjọba àwa-ara-wa Nàìjíríà tuntun jẹ́ àjọ̀sepọ̀ àwọn ẹgbẹ́.
Nigerian People's Congress ni ẹgbẹ́ tí àwọn ará Àríwá tí wọ́n tún jẹ́ Mùsùlùmí ń darí.smi ti Ahmadu àello ati Abubakar Tafawa Bewa to di Alakosoàkọ́kọ́ ẹ́yì òmìnira. Àti ẹgbẹ́ èyítiAlákòóso Àgbà ti awon tíỌmọ Ígbòwọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kìrìstẹ́nì ń jẹ́ ìdarí National Council of Nigeria and the Cameroons , NíNC) ti Nnamdi Aie, to di Gomina-bínibíaàkọ́kọ́ ní ko ni 1960,órí olí i.òNi átakòlataẹgbẹ́iìlọsíwájúsiwaju Action Groupwà,Ati àwọn Yorùbá ti Obafemi Awṣe woórí olori.[20]
Ìpinnu ọdún 1961 fún Apáagúúsù Kameroon láti darapọ̀ mọ́ orílè-èdè Kameroon nígbàtí Apáàríwá Kameroon dúró sí Nàìjíríà fa àìdọ́gba nítorí pé apá àríwá wá tóbi ju Apáagúúsù lọ gidigidi. Nàìjíríà pínyà lọ́dọ̀ Britani pátápátá ní 1963 nípa sísọ ara rẹ̀ di ilẹ̀ Apapo Olominira, pẹ̀lú Azikiwe gẹ́gẹ́ bi Aare àkọ́kọ́. Rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ ní Agbegbe Apaiwoorun lẹ́yìn ìbò 1965 nígbà tí i Nigerian National Democratic Party gba ìjọba ibẹ̀ lọ́wọ́ ọ AG.
Àìdọ́gba yìí àti ìbàjẹ́ ètò ìdìbòyàn tí olóṣèlú fà ní 1966 dé àwọn ìfipágbajọba ológun léraléra. Àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní Oṣù Ṣẹrẹ ti àwọn ọ̀dọ́ olóṣèlú alápáòsì lábẹ́ ẹ Major Emmanuel Ifeajuna àti Chukwuma Kaduna Nzeogwu. Ó kù díẹ̀ kó yọrí sí rere - àwọn olùfipágbàjọba pa Alákòóso Àgbà, Sir Abubakar Tafawa Balewa, Asolórí Agbègbè Apáàríwá Nàìjíríà, Sir Ahmadu Bello, ati Asolórí Agbègbè Apáìwọ̀oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, Sir Ladoke Akintola. Bó tilẹ̀ jẹ́ báyìí, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn olùfipágbàjọba náà kò le bẹ̀rẹ̀ síní ṣe ìjọba nítorí ìṣòro bí wọn yíó ti ṣé, nítorí èyí Nwafor Orizu, adelédè Ààrẹ jẹ́ mímú dandan láti gbé ìjọba fún Ile-ise Ologun Adigun Naijiria lábẹ́ ẹ Apàṣẹ Ọ̀gágun JTY Aguyi-Ironsi.
Irúfẹ́ òfin mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní Nàìjíríà.
Nàìjíríà ní ẹ̀ka ìdájọ́ ọ ti Ilé-Ẹjọ́ Gíga jùlo ilẹ̀ Nàìjíríà, ó jẹ́ èyí tó lágbára jù lọ.
Ní kété tí ó gba òmìnira ní 1960, Nàìjíríà sọ Ìsọ̀kan Áfríkà di ààrin-gbùngbùn òfin òkèèrè rẹ̀, Ó sì kópa ńlá nínú u ìgbógun ti ìjọba Ìyàsọ́tọ̀-Ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní South Africa. Ìyapa kan kúrò ni ìbáṣepọ̀ pẹ́kípẹ́kí tí Nàìjíríà bá Israel ṣe yípo gbogbo 1960s. Israel sonígbọ̀wọ́ àti àmójútó fún kíkọ́ àwọn ilé asòfin Nàìjíríà.
Òfin Òkèère Nàìjíríà rí ìdánwò ní 1970s lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè náà jáde kúrò nínú Ogun Abẹ́lé nísọ̀kan. Ó dúró ti àwọn akitiyan tó lòdì sí ìjọba àwọn òyìnbó péréte ní ẹkùn Gúúsù Áfríkà. Nàìjíríà dúró ti ẹgbẹ́ ẹ African National Congress pẹ̀lú u bó ṣe pọkàn pọ̀ nínú ìpinnu rẹ̀ nípa ìjọba South Africa àti àwọn ipa ológun wọn ní Gúúsù Áfríkà. Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀dádáálẹ̀ ẹgbẹ́ ẹ Organisation for African Unity (tó di African Union) Ó sì ti ní ipa tó kàmọ̀nmọ̀ ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà àti ní Áfríkà lápapọ̀. Nàìjíríà ṣe akitiyan ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà, ó sì tún ṣe aṣáájú fún Economic Community of West African States (ECOWAS) àti ECOMOG (pàápàá nígbà ogun abẹ́lé ní Liberia àti Sierra Leone) – tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ọrọ̀-ajé àti ti ológun ní sísẹntẹ̀lé.
Pẹ̀lú ìdúró tó so mọ́ Áfríkà yí, Nàìjíríà rán àwọn ikọ̀ lọ sí Congo ní ìtẹ̀lé àṣẹ Àjọ àwọn Orílẹ̀-èdè kété lẹ́yìn òmìnira (ó sì ti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ láti ìgbà náà). Nàìjíríà tún ṣe ìtìlẹyìn fún orísìírísìí ẹgbẹ́ ẹ Áfríkà àti àwọn ìdìde fún ìjọba tiwa-n-tiwa ní àwọn 1970s, tó fi mọ́ kíkó ìtìlẹyìn jọ fún MPLA ní Angola àti SWAPO ní Namibia, àti ṣíṣe ìtìlẹyìn fún àtakò sí àwọn ìjọba eléèyan pérété ti àwọn Potogí ní Mozambique àti Rhodesia. Nàìjíríà sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Non-Aligned Movement. Ní ìparí oṣù Belu ní 2006, Nàìjíríà ṣe àkójọ ìpàdé e Áfríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà ní Abuja láti fi gbé nǹkan tí àwọn olùkópa kan pè ní ìbáṣepọ̀ "Gúúsù–Gúúsù" lórísirísìí ọ̀nà lárugẹ. Nàìjíríà tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ilé-Ẹjọ́ Ìwàọ̀daràn Káríayé àti Àjọni àwọn Orílẹ̀-èdè . Wọ́n yọọ́ kúrò nínú u tàsọgbẹ̀yìn fún ìgbà díẹ̀ ní 1995 nígbà ìṣèjọba Abacha.
Nàìjíríà ti jẹ́ olùkópa takuntakun nínú ọjà epo àgbáyé láti 1970s,ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ OPEC, èyí tó darapọ̀ mọ́ ní 1971. Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òǹtà epo gbòógì jẹyọ nínú àwọn ìbáṣepọ̀ mímì pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ti dàgbà sókè, pàápàá Amẹ́ríkà, àti pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣì ń dàgbà sókè.
Láti 2000, ìsòwò láàrin Ṣáínà-Nàìjíríà ti ga sókè sí i. Ìpọ̀síi nínú u òwò ti lé ní mílíọ̀nù 10,384 dọ́là láàrin orílẹ̀-èdè méjèèjì láàrin 2000 sí 2016. Àmọ́, òwò láàrin Sáínà àti Nàìjíríà ti di ọ̀rọ̀ òṣèlú ńlá fún Nàìjíríà. Èyí jẹyọ nínú u pé ìtàjáde àwọn Sáínà jẹ́ ọgọ́rin nínú u ọgọ́rùn-ún gbogbo òwò. Èyí mú àìdọ́gba wá, pẹ̀lú u bí Nàìjíríà ṣe ń kó ọjà ìlọ́po mẹ́wàá wọlé ju ti Sáínà lọ. Bẹ́ẹ̀, ọrọ̀-ajé Nàìjíríà ti ń farati àwọn ìkówọlé ọjà olówó-pọ́ọ́kú láti fi gbéra, èyí sì mú ìdínkù wá nínú u Ìsòwò Nàìjíríà lábẹ́ irú ètò bẹ́ẹ̀.
Ní ìtẹ̀síwájú pẹ̀lú u òfin òkèèrè tó so mọ́ Áfríkà, Nàìjíríà mú àbá wá fún níná owó kan náà ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà tí á máa jẹ́ Eco lábẹ́ ẹ èrò pé náírà ló máa wò ó dàgbà ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Ọ̀pẹ, 2019; Ààrẹ Alassane Ouattara ti Ivory Coast pẹ̀lú u Emmanuel Macron àti púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè UEMOA, kéde pé àwọn kàn máa yí orúkọ CFA franc padà ní kàkà kí àwọn rọ́pò rẹ̀ bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀. Ní 2020, wọ́n ti gbé ètò owó o Eco náà tì di 2025.
Ojúṣe àwọn ológun Olómìnira Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ni láti dáàbò bo ilẹ̀ Nàìjíríà, gbígbésókè ìjẹlógún àbò Nàìjíríà àti ìtìlẹyìn ìtiraka ìgbèrò àlàáfíà àgàgà ní Ìwọ̀oòrùn Áfríkà.
Iṣẹ́ ológun Nàìjíríà ní Ilé-Isẹ́ Ológun Akogun,Ilé-Isẹ́ Ológun Ojú Omi, àti Ilé-Isẹ́ Ológun Ojú Afẹ́fẹ́.
Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà,Ilé-Isẹ́ Ológun Nàìjíríà ti kópa nínú Ìgbèrò Àlàáfíà ní Áfríkà. Ilé-Isẹ́ Ológun Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí i ìkan nínú ECOMOG ti kópa gẹ́gẹ́ bí i olùfbèrò àlàáfíà ní Liberia ní 1990, Sierra Leone ní 1995, Ivory Coast àti Sudan.
Nàìjíríà wà ní apá Ìwọ̀oòrùn Áfríkà ní Ikun-omi Guinea, àpapọ̀ ilẹ̀ ẹ rẹ̀ sì fẹ̀ níwọ̀n 923,768 km2 (356,669 sq mi), èyí jẹ́ kó jẹ́ orílẹ̀-èdè 32ji tó tóbi jù lọ lágbàáyé lẹ́yìn in Tanzania. Ibodè rẹ̀ pẹ̀lú Benin tó 773 km, ti Niger tó 1497 km, ti Chad tó 87 km àti ti Kamẹrúùnù tó 1690 km; bákan náà àlà etí-odò rẹ̀ tó 853 km. Ibi tó ga jù lọ ní Nàìjíríà ni Chappal Waddi ní 2419 m (7936 ft). Àwọn odò gbangba ibẹ̀ ni Odo Oya àti Odo Benue tí wọ́n já pọ̀ ní Lokoja, láti ibi tí wọ́n ti sàn lọ sínú Okun Atlantiki láti Delta Naija.
Bákan náà, Nàìjíríà jẹ́ gbọ̀ngán pàtàkì fún orísìírísìí ẹranko àti nǹkan abẹ̀mí pàtàkì. Agbègbè tó ní àwọn orísìírísìí labalaba jùlọ láyé ni agbègbè Calabar ní Ipinle Cross River. Àwọn ọ̀bọ agbélẹ̀ ń gbé ní Gúúsù-Ìlà-oòrùn Nàìjíríà àti Kamẹrúùnù nìkan.
Ojúilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́ orísìírísìí. Ní Gúúsù, ojú-ọjọ́ jẹ́ ti ojoinuigbo amuooru níbi tí òjò ọdọọdún tó 60-80 inches (1,524 — 2,032 mm) lọ́dún. Ní apá gúúsù-ìlà-oòrùn ní Àwọn Ìwúlẹ́ Obudu wà.
Nàìjíríà jẹ́ pípín sí mẹ́rìndínlógójì ipinle 36 pọ̀mọ́ Agbègbè Olúìlú Àpapọ̀ kan; àwọn wọ̀nyí náà jẹ́ pípín sí agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ 774.
Ìlú mẹ́fà ní Nàìjíríà ni àwọn oníbùgbé tó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kan tàbí púpọ̀ jùlọ: Èkó, Kano, Ibadan, Kaduna, Port Harcourt àti Benin.
Awon Ipinle:
Agbegbe: Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀
Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan láàrin àwọn ọjà tó ń gbéra sókè nítorí àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì púpọ̀ tó ní, ìnáwó, ìbánisọ̀rọ̀, òfin àti ìrìnnà àti pàsípàrọ̀ ìpínwó (Ilée-pàsípàrọ̀ Ìpínwó Nàìjíríà) tó jẹ́ èkejì tó tóbi jù lọ ní Áfríkà. Nàìjíríà ní 2007 jẹ́ 37th lágbàáyé ní Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè. Gẹ́gẹ́ bí Economic Intelligence Unit àti Ilé-Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe sọ. Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè tí Nàìjíríà fún ìpín agbára ìrajà tí jẹ ìlọ́po méjì láti $170.7 legbegberunkeji ní 2005 dé $292.6 legbegberunkeji ní 2007. Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ti fò láti $692 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 2006 dé $1,754 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní 2007.[21]
Nígbà ọ̀pọ̀ epo àwọn ọdún 1970s, Nàìjíríà dá gbèsè òkèèrè tó tóbi gidi láti ṣe ìnáwó ìdè-ajé-mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí iye owó epo dín ní àwọn ọdún 1980s, ó ṣòro fún Nàìjíríà láti san àwọn gbèsè rẹ̀ padà, èyí fa kó fi owó tó yá sílẹ̀ láìsan kó le ba à kọjú sí bí yíò ṣe san èlé orí owó tó yá nìkan.
Lẹ́yìn ìjíròrò ìjọba Nàìjíríà ní October 2005, Nàìjíríà àti àwọn aṣínilówó Paris Club fi ẹnu kò pé Nàìjíríà le ra gbèsè rẹ̀ padà pẹ̀lú ìdínwó tó tó 60%. Nàìjíríà lo èrè tó jẹ níbi epo láti san gbèsè 40% tó kù, èyí jẹ́ kí $1.15 lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún kejì ó lé sílẹ̀ lọ́dún láti ṣe ètò ìdín àìní. Nàìjíríà di orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ní Áfríkà láti san gbogbo gbèsè (tí ìdíye rẹ̀ jẹ́ $30 lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún kejì) tó jẹ Paris Club padà ní April 2006.
Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè 8th tó ń ta epo pẹtiró láyé, bẹ́ẹ̀ sì ni òun ni ìkẹẹ̀wà tó ní ìpamọ́ epo pẹtiró.
Nàìjíríà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ OPEC. Epo petroleomu kó ipa pàtàkì nínú u okòòwò Nàìjíríà tó ṣírò fún 40% Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdè (GIO) àti 80% iye owó tí ìjọba ń pa.
Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọjà fún Ìbánisọ̀rọ̀-ọ̀ọ́kán tó ń dàgbà sókè kíákíá jù láyé, àwọn ilé-isẹ́ ìbánisọ̀rọ̀-ọ̀ọ́kán bí i MTN, Etisalat, Airtel àti Globacom ni ibùjókòó tó tóbi jù lọ tó sì lérè jù lọ ní Nàìjíríà. [22]
Nàìjíríà ní apá okòòwò ìṣefúnni oní-ìnáwó dídàgbà gidi, pẹ̀lú àdàlù àwọn ilé-ìfowópamọ́ abẹ́le àti káríayé, àwọn ilé-isẹ́ ìmójútó ohun ìní, Ilé-isẹ́ Adíyelófò, àwọn ilé-isẹ́ brokerage, àwọn àjọ aládàáni equity àti àwọn ilé-ìfowópamọ́ ìnáwọlé. [23]
Bákan náà, Nàìjíríà tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan àlùmọ́ọ́nì àti ìmúlò bíi ẹ̀fúùfù aládàánidá, èédú, bauxite, tantalite, wúrà, tin, irin inú-ilẹ̀, òkúta dídán, niobiomu, òjé, ati sinki[24].
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ dáadáa, àwọn ilé-isẹ́ akó-àlùmọ́ọ́nì tí ó mú wọn jáde ò sí.
Iṣẹ́ Àgbẹ̀ jẹ́ èyí tó ń mú owó òkèèrè wọlé fún Nàìjíríà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ [25].
Nígbà kan, Nàìjíríà ló ń ta Ẹ̀pà, Kòkó àti Epo Ọ̀pẹ tó pọ̀ jùlọ sí òkè-òkun àti olùpèsè pàtàkì Coconut, Èso ọsàn, Àgbàdo, Ọkà Bàbà, Ẹ̀gẹ́, Iṣu àti Ìrèké. Bí i 60% àwọn ará a Nàìjíríà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ilẹ̀ tó ṣe é dáko sì wà ṣùgbọ́n tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ gidi [26].
Nàìjíríà ní àwọn ilé-isẹ́ àgbẹ̀ṣe bí i Leather àti Ìhun Aṣọ ní Kano, Abeokuta, Onitsha àti Èkó. Ilé-isẹ́ Ato-ọkọ̀-pọ̀ bí i Peugeot láti Fransi àti Bedford láti Britani tó jẹ́ apá kan lára ilé-isẹ́ ọkọ̀ láti orílẹ̀-èdè Amerika, General Motors;nísìn-ín, àwọn ẹ̀wù t-shirt, ike àti oúnjẹ alágolo.
Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè tí èèyàn pọ̀sí jùlọ ní Áfríkà bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tó jẹ́ gangan kò ì jẹ́ mímọ̀. Àjọ Ìṣọ̀kan Àwọn Orílẹ̀-èdè díye pé iye àwọn èèyàn tó wà ní Nàìjíríà ní 2009 jẹ́ 154,729,000, tí 51.7% nínú u wọn ń gbé ní ìgbèríko tí 48.3% sì ń gbé ní ìlú-ńlá ;àti iye ènìyàn 167.5 ní agbègbè ìlọ́po méjì kìlómítà kan.
Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè kẹjọ tí ó ní àwọn ènìyàn tó pọ̀ jùlọ láyé. Òǹkà ní 2006 fi hàn pé iye ènìyàn tí ọjọ́-orí wọn wà láàrin ọdún 0-14 jẹ́ 42.3%; láàrin ọdún 15-65 sì jẹ́ 54.6%. Òṣùwọ̀n ìbímọ pọ̀ gidi ju òṣùwọ̀n ikú lọ, wọ́n jẹ́ 40.4% àti 16.9% nínú ènìyàn ẹgbẹ̀rún (1000) ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
Nàìjíríà ní bí i ẹ̀ya 250 pẹ̀lú orísìírísìí èdè pẹ̀lú àṣà àti ìṣe orísìírísìí. Àwọn ẹ̀yà ènìyàn tó tóbi jùlọ ni Hausa/Fulani, Yoruba ati Igbo ti àpapọ̀ wọn jẹ́ 68% nígbàtí Edo, Ijaw, Kanuri, Ibibio, Ebira, Nupe àti Tiv jẹ́ 27%,tí àwọn yòókù jẹ́ 7%.Ó jẹ́ mímọ̀ pé Ààrin ìbàdí Nàìjíríà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà bí i Pyem, Goemai, àti Kofyar.
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.