Ìpínlẹ̀ Gombe

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia

Ìpínlẹ̀ Gombe

Ìpínlẹ̀ Gombe jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà sí àríwá àti àríwá-ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Borno àti Ìpínlẹ̀ Yobe, sí gúúsù pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Taraba, sí gúúsù-ìlà-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Adamawa, àti sí ìwọ̀-oòrùn pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Bauchi. Wọ́n sọọ́ lórúkọ fún ìlu Gombe—tí ó jẹ́ olú-ìlú ìpínlẹ̀ àti ìlú tí ó gbòòrò jùlọ—Wọ́n ṣẹ̀da Ìpínlẹ̀ Gombe látara àwọn apa kan Ìpínlẹ̀ Bauchi ní ọjọ́ kìnínní oṣù kẹwàá ọdún 1996.[1]

More information Location, Statistics ...
Ìpínlẹ̀ Gombe
State nickname: Jewel in the Savannah
Location
Thumb
Statistics
Governor
(List)
Mohammed Danjuma Goje (PDP)
Date Created 1 October 1996
Capital Gombe
Area 18,768 km²
Ranked 21st
Population 2006 est. Ranked 33rd
2,353,000
ISO 3166-2 NG-GO
Close

Laaarin àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìpínlẹ̀ Gombe jẹ́ ìpínlẹ̀ kọkànlélógún tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè àti ẹlẹ́ẹ̀kejìlélọ́gbọ̀n ní iye pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù-mẹ́talénídàámẹ́rin-mílíọ́nnù gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún 2016.[2]

Ní ti .ẹ̀yà,àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Gombe láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà, pàápàá àwọn ará Fulani tí wọ́n gbé ní àríwá àti àáríngbùngbùn ìpínlẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Bolewa, Kanuri, àti àwọn ará Hausa nígbàtí ìlà-oòrùn àti àwọn agbègbè gúúsù lóríṣiríṣi kúnfún àwọn ará Cham, Dadiya, Jara, Kamo, Pero, Tangale, Tera, àti àwọn ará Waja. Ní ti ẹ̀sìn, àwọn tí wọ́n pọ̀ jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà (~75%) jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí nígbàtí àwọn ẹlẹ́sìn Kììtẹ́nì àti ẹlẹ́sìn abalaye ò pọ̀, wọ́n wà ní ìdiwọ̀n 20% àti 5%, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lè.[3]



Itokasi

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.