From Wikipedia, the free encyclopedia
Ẹ̀yà àwọn Ènìyàn dúdú jẹ́ ọ̀kqn ìpínsísọ̀rí àwọn èya lágbàáyé, látàrí ìrísí àwọ̀ àti ìrísí wọn. Àmọ́ ṣá, kìí ṣe.gbogbo ẹni tí abá pè ní Aláwọ̀ dúdú náà ni wọ́n dú láwọ̀, bí kò ṣe wípé wa fi ma ń ṣàdáyanrí irúfẹ́ ẹ́yà tí ẹnìkan tabí ẹlòmíràn jẹ́ ni. Ní ìlú àwọn aláwọ̀ funfun, wọ́n ma ń tọ́ka sí ẹni tí kò bá fín láwọ̀ bíi tiwọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn dúdú. Wọ́n sábà ma ń lo gbólóhùn "Dúdú" fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti Sub-Saharan Africa àti àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ti wá láti Oceania. Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn Áfíríkà kìí nàka kìí le ara wọn ní "Dúdú" gẹ́gẹ́ bí àwọn aláwọ̀ funfun ṣe ma ń tọ́ka sí wọn. Wọ́n ka gbólóhùn "Dúdú kún èdè ìperí àwọn aláwọ̀ funfun.[1][2] The AP Stylebook[1][2] [3] Ọ̀nà oríṣiríṣi ni àwọn ènìyàn àwùjọ kọ̀ọ̀kan ma ń lò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá aláwọ̀ dúdú ni ẹnìkan tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àmọ́ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ti yí padà ní òde òní. Púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé lónìí ni wọ́n lè pe ẹnìkan ní aláwọ̀ dúdú látàrí àwọ̀ tàbí irúfẹ́ ipò tí ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà ní àwùjọ àwọn ènìyàn kan. Ní orílẹ̀-èdè Bríténì, wọ́n lè tọ́ka sí Dúdú gẹ́gẹ́.bí ẹ́ni àwọ̀ rẹ̀ dúdú, tí kìí ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀ Yúróòpù. Ní ẹkùn Australasia, àwọn ma ń tọ́ka sí Dúdú gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìran wọn dú láwọ̀l. Ní ọkàn ẹnikẹ́ni, àwùjọ, Ìlú, agbègbè tàbí orílẹ̀-èdè yóòwù lágbàáyé, gbólóhùn Dúdú jẹ́ gbólóhùn ijọ́un, tí ó ń tàbùkù, kó ẹrẹ̀ báni tabí gbólóhùn ìfojú pani rẹ́ tí kò yẹ.kí ẹnikẹ́ni ó ma lò láti ṣàpèjúwe, tọ́ka, tàbí ṣàdáyanrí ẹnìkan, tàbí àwùjọ ènìyàn kankan lágbàáyé. Bí kìí ṣe láti fi sọ irúfẹ́ àwọ̀ tí irúfẹ́ ẹni tàbí àwọn ènìyàn náà ní. [4]
Ọpọ àwùjọ àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú apá Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti wà ṣáájú kí wọ́n ó to ní ìmọ̀ àti òye a ń kọ̀tàn nípa àwọn ènìyàn. Àwọn mìíràn lára wọn jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀dó sí àwọn ìletò káàkiri látàrí òwò àti kárà-kátà tí wọ́n ma ń ṣe, tàbí lẹ́yìn tí àwọn Lárúbáwá kò wọn lẹ́rú ní ńkan bí ọ̀rùndún méje sèyìn (7th centuries). [5][6]
In the 18th century, the Moroccan Sultan Moulay Ismail "the Warrior King" (1672–1727) raised a corps of 150,000 black soldiers, called his Black Guard.[7][8]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.