Ogun Abele Nigeria
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ogún Abẹ́lé ilẹ̀ Nàìjíríà wáyé láàárín ọjọ́ Kẹfà Oṣù Okúdù Ọdún 1967 sí ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Ṣẹ́ẹ́rẹ́: tí a tún mọ̀ sí (Ogun Nàìjíríà - Biafra tàbí Ogun Biafra) jẹ́ Ogun Abẹ́lé tí ó wáyé láàárín ìjọba Nàìjíríà àti orílè-èdè Biafra, ìpínlẹ̀ tí ó fé dádúró tì ó ti fẹ́ gba òmìnira kúrò lára Nàìjíríà ní ọdún 1967. Ọgágun Yakubu Gowon ni ó ń darí Orílẹ̀èdè Nàìjíríà Lt. Colonel Odumegwu Ojukwu sí ń darí Biafra. Èròngbà àwọn olùfẹ́ ẹ̀yà Ìgbò tí wọ́n rò pé àwọn kò lè bá ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe pọ̀ mọ torí pé àwọn Mùsùlùmí ẹ̀yà Haúsá-Fúlàní tí àríwá Orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí jẹ gàba ní Biafra. Ìyọrísí ìkọlù yìí láti rògbòdìyàn ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, ẹ̀yà, ajẹmáṣà àti ẹ̀sìn ló bí pínpín Nàìjíríà láti ọdún 1960 sí 1963. Lára àwọn aṣokùnfà ogun ní ọdún 1966 ni ìjà ẹ̀sìn àti ìṣègbè ẹ̀yà Ìgbò ní Apá Àríwá Nàìjíríà. Ìdìtẹ̀gbàjọba, àti ìrẹ́jẹ àwọn Ìgbò ní apá àríwá Naijiria. Bákan náà Ìjẹ gàba lórí ìgbéjáde epo rọ̀bì tó lérè gọbọi lórí ní apa Niger Delta náà kópa ribiribi nínú ogun abẹ́lé náà.
Láàárín ọdún kan, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti yí gbogbo kọ̀rọ̀-kọ́ndú ilẹ̀ Ìgbò Biafara po tí ó fi mọ́ orísun epo tí ó wà ní ìlú Port Harcourt.[citation needed]. Wọ́n mọ odi yí wọn ká tínwọn kò sì gbà kí ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Ìgbò ó jáde síta, èyí f a ebi ọ̀pàgbà f'ọwọ́-mẹ́kẹ́ fún tẹ́rú tọmọ wọn.[40] Láàárín ọdún méjì ati abọ̀ tí ogun náà fi wáyé, iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Ìgbò tí wọ́ ṣ'aláìsí láti ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọgọ́rún kan, nígbà tí iye àwọn tí wọ́n ṣ'aláìsí látàrí ebi òpàpàpàlà jẹ́ mílíọ́nù lọ́nà ọgọ́rùn-un márùn-ún ènìyàn.[41]
Ogun Abélé ilẹ̀ Nàìjíríà | |||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Part of Cold War àti decolonisation of Africa | |||||||||
Soldiers in the Nigerian Civil War.jpg Marching soldiers of the Biafran Armed Forces[1] | |||||||||
| |||||||||
Àwọn agbógun tira wọn | |||||||||
| |||||||||
Supported by:
![]() ![]() ![]() ![]() Àdàkọ:Country data People's Republic of Bulgaria[7] Àdàkọ:Country data Ethiopian Empire Ethiopia[8] ![]() ![]() ![]() ![]() ![]() ![]() ![]() ![]() ![]() |
|||||||||
Àwọn apàṣẹ | |||||||||
Foreign mercenaries:
| |||||||||
Agbára | |||||||||
![]() |
Àdàkọ:Country data Biafra Biafran Armed Forces: | ||||||||
Òfò àti ìfarapa | |||||||||
Combatants killed: 45,000[32]–100,000[35][36]
Biafran civilians died from famine during the Nigerian naval blockade[37] Displaced: 2,000,000–4,500,000[38] Refugees: 500,000[39]–3,000,000[citation needed] |
Nígbà tí yóò fi di àárín ọdún 1968, àwọn oníròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ń fi àwòrán àwọn àgbà àti ọmọdé tí ebi ti sọ di aláabọ̀ ara nínú àwọn ẹ̀yà ìgbò léde nínú àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n ń jáde ní àwọn orílẹ̀-èdè òkèrè[citation needed]. Àwòrán àwọn tí ebi ń pa wọ̀nyí beeẹ̀ sí ń mú kí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ó beeẹ̀ sí ń fi oju àánú wo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tí ó sì mú kí àwọn àjọ 3lẹ́yinjú àánú tí kìí ṣe ti ìjọba ó ma dá owó , ounje , aṣọ àti àwọn ohun ìgbáyé-gbádùn mìíràn ránṣẹ́ sí wọn. Orílẹ̀-èdè United Kingdom àti Soviet Union ni wọ́n fẹ̀yìn pọn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti bori Biafra nígbà náà, nígbà tí orílẹ̀-èdè France àti Isreal ṣagbátẹrù fún àwọn Biafra láti kojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà padà. Àmọ́ àwọn Amẹ́ríkà ní ti wọn kò ṣ'ègbè lẹ́yìn ẹnìkọkan, wọ́n kò fara mọ́ ìfìyà-jẹni tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń fi jẹ àwọn Igbo yí, bákan náà ni wọ́n bu ẹnu atẹ́ lu ìgbàẹ́sẹ̀ ìyapa àwọn Biafra kúrò lára orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[42] [43][44]