Ọmọnìyàn
From Wikipedia, the free encyclopedia
Awon ọmọnìyàn tabi omo eniyan ni awon iru Homo sapiens Homo sapiens (Latin: eniyan oloye; "wise man" tabi eniyan onimo; "knowing man"),[1][2] iru Homo kan soso to si wa laye (extant) abaratan primate elesemeji ninu Hominidae, ebi great ape. Sugbon, nigba miran o nje lilo lati tokasi eyi keyi toba je abaratan Homo.
Ènìyàn | |
---|---|
Ènìyàn akọ (òsì) àti abo (ọ̀tún) | |
Ipò ìdasí | |
Least Concern (IUCN 3.1) | |
Ìṣètò onísáyẹ́nsì | |
Àjákálẹ̀: | |
Ìjọba: | |
Ará: | Chordata |
Superclass: | Tetrapoda |
Ẹgbẹ́: | |
Infraclass: | Eutheria |
Ìtò: | |
Suborder: | Haplorrhini |
Infraorder: | Simiiformes |
Parvorder: | Catarrhini |
Superfamily: | Hominoidea |
Ìdílé: | Hominidae |
Subfamily: | Homininae |
Ẹ̀yà: | Hominini |
Ìbátan: | Homo |
Irú: | H. sapiens |
Irú-ọmọ: | H. s. sapiens |
Ìfúnlórúkọ mẹ́ta | |
Homo sapiens sapiens Linnaeus, 1758 |
Awon eniyan ni opolo todagba daada, to le e ni ironu afoyemo, ede, ifinuwo, ati isojutu isoro. Agbara opolo yi, lapapo mo inaro ara to jagbekun awon owo lati fowo se awon ohun, gba awoniyan laaye lati lo awon ohun isise daada ju awon iru miran lo. Mitochondrial DNA ati eri adikuta (fossil) fihan pe awoneniyan oni berelati Africa bi odun 200,000 seyin.[3] Pelu olukuluku eniyan ni gbogbo orile ayafi ni Antarctica, awon eniyan je awon iruaraleaye. Iye awon eniyan je 6.8 legbegberunkeji ni November 2009.[4]
Gege bi awon higher primates, adanida awon eniyan je alawujo. Sibesibe, awon eniyan je eyi soso to nlo sistemu ibanisoro lati so tenu ara re, pasiparo iyenu, ati igbajo. Awon eniyan da ifidimule awujo tosoro to ni opo awon eniyan ti won fowosowopo ati ti won takorawon, lati inu awon ebi de inu awon orile-ede. Awon ibarasepo awujo larin awon eniyan ti sedasile orisirisi opo iyi, ise awujo, ati awon igbese, ti lapapo won da ipilese awujo eniyan.
Awon eniyan se pataki nipa ife won lati loye ati kopa lori ayika won, won wa lati salaye ati lo awon isele adanida nipa sayensi, imoye, itan awaso, ati esin. Isawari adanida yi ti mu idagbasoke awon ohun isise didagba ati ogbonise, ti won je jijogun lati inu asa; awon eniyan nikan ni iru eda ti a mo ti won le se ina, se onje won, wo aso, ti won si le lo opolopo awon technologies miran.