Niger Delta jẹ́ ilẹ̀ àti iyẹ̀pẹ̀ tí ó sàn láti Odò Ọya tí ó sì wà ni Gulf of Guinea ti Atlantic Ocean, Nàìjíríà.[1][2] Ó wà lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà.

Thumb
Àwòrán orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó ń ṣe àfihàn àwọn Ìpínlẹ̀ Nàìjíríà tí ó wà lára Niger Delta, àwọn orílẹ̀ èdè náà ni: 1. Abia, 2. Akwa Ibom, 3. Bayelsa, 4. Cross River, 5. Delta, 6. Edo, 7.Imo, 8. Ondo, 9. Rivers
Thumb
Àwòrán Niger Delta láti ọ̀furufú.

Ọ̀pọ̀lopọ̀ lọ ń gbé lórí Niger Delta, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì mọ ibè sí Oil Rivers nítorí ibè ni wọ́n ti ń ṣe epo Pupa ní Nàìjíríà.[3] Ibẹ̀ náà sì jẹ́ ibi tí ọ̀pọ̀lopọ̀ epo rọ̀bì.[4][5]

Ilẹ̀ Niger Delta

Niger Delta ní ilẹ̀ tí ó tó 70,000 km2 (27,000 sq mi), ó sì gbà tó 7.5% gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn Ìpínlẹ̀ tí ilẹ̀ náà dé ni Bayelsa, Delta, àti Ìpínlẹ̀ Rivers. Niger Delta ló pín Bight of Benin àti Bight of Bonny níyà nínú Gulf of Guinea.[6]

Àwọn ènìyàn Niger Delta[4]

Thumb
Ọkàn lára àwọn ère àwọn ènìyàn Ijaw

Àwọn ènìyàn tí ó tó mílíọ̀nù ókànlélógbọ̀n ni ó gbé ní Niger Delta[7] àwọn ẹ̀yà tí ó wà níbè sì tó ogójì, àwọn ẹ̀yà bi Ukwuani, Abua, Bini, Ohaji/Egbema, Itsekiri, Efik, Esan, Ibibio, Annang, Oron, Ijaw, Igbo, Isoko, Urhobo, Kalabari, Yoruba, Okrika, Ogoni, Ogba–Egbema–Ndoni, Epie-Atissa àti Obolo, wọ́n sì ń sọ èdè tí ó tó ọ́ta-din-lẹwá-lé-nígba(250). Díè nínú àwọn èdè yìí ni èdè Ijaw, Ibibio-Efik, Igboid, Itsekiri, Central Delta, Edoid, àti Àwọn èdè irú Yorùbá,

Àwọn Ìtọ́kasí

Wikiwand in your browser!

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.

Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.