Orílẹ̀ èdè America
From Wikipedia, the free encyclopedia
Orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan àwọn Ìpínlẹ̀ Amẹ́ríkà tabi Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (USA tabi US ní sọ́kí ní gẹ̀ẹ́sì), tàbí Amerika ni soki, jẹ́ orílé-èdè ijoba àpapò olominira pèlú iwe-ofin ibagbepo tí ó ni adota ipinle, agbegbe ijoba-apapo kan ati agbegbe merinla, ti o wa ni Ariwa Amerika. Ilẹ̀ re fe lati Òkun Pasifiki ni apa iwoorun de Òkun Atlántíkì ni apa ilaorun. O ni bode pelu ile Kanada ni apa ariwa ati pelu Meksiko ni apa guusu. Ipinle Alaska wa ni ariwaiwoorun, pelu Kanada ni ilaorun re ati Rosia ni iwoorun niwaju Bering Strait. Ipinle Hawaii je agbajo erekusu ni arin Pasifiki. Orile-ede awon Ipinle Aparapo tun ni opolopo agbegbe ni Karibeani ati Pasifiki.
Orílẹ̀-èdè Ìṣọ̀kan àwọn Ìpínlẹ̀ Amẹ́ríkà United States of America
| |
---|---|
Motto: In God We Trust (official) [E pluribus unum] error: {{lang}}: text has italic markup (help) (From Many, One; Latin, traditional) | |
Orin ìyìn: "The Star-Spangled Banner" | |
Olùìlú | Washington, D.C. |
Ìlú tótóbijùlọ | New York City |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | None at federal level (English is an official language in 28 states)1 |
National language | English (de facto)2 |
Orúkọ aráàlú | American |
Ìjọba | Federal presidential constitutional republic |
• Aare | Joe Biden |
• Igbakeji Aare | Kamala Harris |
• Agbeuso Ile Asoju | Mike Johnson |
• Adajo Agba | John Roberts |
Independence from Great Britain | |
• Declared | July 4 1776 |
• Recognized | September 3 1783 |
Ìtóbi | |
• Total | 9,826,630 km2 (3,794,080 sq mi) (3rd3) |
• Omi (%) | 6.76 |
Alábùgbé | |
• 2024 estimate | 339,669,000[1] (3rd4) |
• 2000 census | 281,421,906[2] |
• Ìdìmọ́ra | 31/km2 (80.3/sq mi) (144th) |
GDP (PPP) | 2007 estimate |
• Total | $13.543 trillion[3] (1st) |
• Per capita | $43,444 (4th) |
GDP (nominal) | 2007 estimate |
• Total | $13.794 trillion[3] (1st) |
• Per capita | $43,594 (9th) |
Gini (2006) | 47.0[4] Error: Invalid Gini value |
HDI (2005) | 0.951 very high · 12th |
Owóníná | United States dollar ($) (USD "$") |
Ibi àkókò | UTC-5 to -10 |
• Ìgbà oru (DST) | UTC-4 to -10 |
Àmì tẹlifóònù | 1 |
Internet TLD | .us .gov .mil .edu |
|
Pelu 3.79 egbegberun ilopomeji maili (9.83 million km2) ati iye to ju 309 egbegberun eniyan lo, awon Ipinle Aparapo je orile-ede totobijulo keta tabi kerin bii apapo iye aala, ati iketa totobijulo bii aala ile ati bi awon olugbe. O je kan ninu awon orile-ede agbaye to ni opolopo eya eniyan ati asapupo, eyi je nitori ikoreokere lati opo awon orile-ede.[5] Okowo awon Ipinle Aparapo ni okowo orile-ede to tobijulo lagbaye, pelu idiye GIO 2009 to je $14.3 egbegberunketa (idamerin GIO oloruko lagbaye ati idamarun GIO agbaye fun ipin agbara iraja).[6]
Awon eniyan abinibi ti won wa lati Asia ti budo si ori ibi ti orile-ede awon Ipinle Aparapo wa loni fun egberun lopo odun. Awon olugbe Abinibi ara Amerika din niye gidigidi nitori arun ati igbogunti leyin ibapade awon ara Europe. Orile-ede awon Ipinle Aparapo je didasile latowo awon ileamusin metala ti Britani to budo si egbe Okun Atlantiki. Ni ojo 4 Osu Keje, 1776, won se Ifilole Ilominira, eyi kede eto won fun iko araeni ati idasile isokan alafowosowopo won. Awon ipinle asagun yi bori Ileobaluaye Britani ninu Ogun Ijidide Amerika, eyi ni ogun alamusin fun ilominira akoko to yori si rere.[7] Ilana-ibagbepo ile awon Ipinle Aparapo lowolowo je gbigba bi ofin ni ojo 17 Osu Kesan, 1787; itowobosi ni odun to tele so awon ipinle di apa orile-ede olominira kan na pelu ijoba apapo to lagbara. Awon Isofin awon Eto, to ni atunse mewa si ilana-ibagbepo ti won semudaju awon eto ati ainidekun araalu, je titowobosi ni 1791.
Ni orundun 19th, awon Ipinle Aparapo gba ile lowo France, Spain, Ileoba Aparapo, Mexico, ati Rosia, o si sefamora Ile Olominira Teksas ati Ile Olominira Hawaii. Ijiyan larin awon ipinle ni Guusu ati awon ipinle ni Ariwa lori awon eto awon ipinle ati igbegun oko eru lo fa Ogun Abele Amerika ti awon odun 1860. Isegun ti Ariwa dena ipinya, o si fa opin oko eru ni Amerika. Nigba ti yio fi to awon odun 1870, okowo orile-ede awon Ipinle Aparapo ile Amerika ni eyi ti o tobijulo lagbaye.[8] Ogun Spein ati Amerika ati Ogun Agbaye Akoko so Amerika di orile-ede alagbara ologun. Leyin Ogun Agbaye Keji o di orile-ede akoko to ni ifija inuatomu, o si tun di omo egbe tikoye ni Ileigbimo Abo Agbajo awon Orile-ede Aparapo. Opin Ogun Koro ati Isokan Sofieti mu ki awon Ipinle Aparapo o di orile-ede alagbara nikan to ku. Amerika siro fun idameji ninu marun inawo ologun lagbaye be sini o tun je akopa asiwaju ninu okowo, oloselu ati asa lagbaye.[9]