Ìpínlẹ̀ Òndó
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Ondo jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù-ìwọ̀oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. wọ́n da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejí ọdún 1976 látara àwọn Ìpínlẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn tẹ́lẹ̀ rí.[4] Ìpínlẹ̀ Ondo pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ekiti sí àríwá, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Edo sí ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Delta sí gúúsù-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ogun sí gúúsù-ìwọ̀ oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Osun sí àríwá-ìwọ̀ oòrùn, àti pẹ̀lú Atlantic Ocean sí gúúsù.[5] Tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Akure, ìyẹn olú-ìlu ẹkùn-ìjọba Akure àtijọ.[6] Ìpínlẹ̀ Ondo ni igbó mangrove-swamp wà lẹ́ba àwọn ìgbèríko ìlu Benin.[7]
Ondo State State nickname: Sunshine State | ||
Location | ||
---|---|---|
![]() | ||
Statistics | ||
Governor (List) |
Lucky Aiyedatiwa (-) | |
Date Created | 3 February 1976 | |
Largest City | Ondo | |
Capital | Akure | |
Area | 14,606 km² Ranked 25th | |
Population 1991 Census 2005 estimate |
Ranked 20th 3,884,485 4,011,407 | |
ISO 3166-2 | NG-ON |
Ondo | |||
---|---|---|---|
![]() | |||
| |||
Nickname(s): | |||
![]() Location of Ondo State in Nigeria | |||
Coordinates: 7°10′N 5°05′E | |||
Country | Nigeria | ||
Date created | 3 February 1976 | ||
Capital | Akure | ||
Government | |||
• Body | Government of Ondo State | ||
• Governor (List) | Lucky Aiyedatiwa (APC) | ||
• Deputy Governor | Olayide Adelami (APC) | ||
• Legislature | Ondo State House of Assembly | ||
• Senators | C: Akinyelure Patrick Ayo (APC) N: Robert Ajayi Boroffice (APC) S: Nicholas Tofowomo (PDP) | ||
• Representatives | List | ||
Area | |||
• Total | 15,500 km2 (6,000 sq mi) | ||
Population (2006 census)1 | |||
• Total | 3,460,877[1] | ||
• Rank | 18th of 36 | ||
GDP (PPP) | |||
• Year | 2007 | ||
• Total | $8.414 billion[2] | ||
• Per capita | $2,392[2] | ||
Time zone | UTC+01 (WAT) | ||
postal code | 340001 | ||
ISO 3166 code | NG-ON | ||
HDI (2018) | 0.606[3] medium · 16th of 37 | ||
^1 Preliminary results |
Tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ njẹ́ "Sunshine State", Ìpínlẹ̀ Ondo jé ọ̀kàndìnlógún Ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,[8] tí ó sì jẹ́ ìpínlẹ̀ karùndínlọ́gbọ̀n tó fẹ̀ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ilẹ̀ gbígbà.[9] Yorubani ó gbilẹ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà,[10][11] èdè Yorùbá ni wọn ń sọ jù níbẹ̀.[12] Ilé-iṣẹ́ epo-bẹntiróò ni ó gbilẹ̀ jù gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé ní ìpínlẹ̀ náà. òwo Cocoa, wíwa asphalt, àti àwọn ọ̀gọ̀rọ̀ iṣẹ́ etí òkun pẹ̀lú èto ọrọ̀-ajé ìpínlẹ̀ náà.[13] Ilé àwọn òkè Idanre ni, tí ó kó ipa tó ga jùlọ nínú ìdajì àwọn agbègbè ìwọ̀-oòrùn tí ó làmìlaka lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó ga ju ìwọn ọgọ́run mítà lọ ní títayọ.
Ìpínlẹ̀ náà ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, àwọn tí ó jẹ́ gbòógì náà nìwọ̀nyí Akoko, Akure, Okitipupa, Ondo, Ilaje, Idanre àti Owo. Púpọ̀ nínú àwọn ará ìpínlẹ̀ náà ń gbé ní àwọn ilu tí ó lajú. Àwọn fáfitì ìjọba tí ó gbajúgbajà ní ìpínlẹ̀ Ondonáà nìwọ̀nyí Federal University of Technology Akure, Akure Ondo State University of Science and Technology, Okitipupa University of Medical Sciences, Ondo, Ondo àti Adekunle Ajasin University, Akungba Akoko.[14]
Ìpínlẹ̀ Ondo ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, wọn sì ni:
Akeredolu Oluwarotimi Odunayo[16] jẹ́ gómìnà lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Ìpínlẹ̀ Ondo.[17] Gómìnà Oluwarotimi Odunayo Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu "All Progressives Congress" (APC) ni wọ́n ṣe ìbúra fún bọ́sípò ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejì, ọdún 2017 jẹ lẹ́yìn Olusegun Mimiko.[18] Lucky Aiyedatiwa ni igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo.[19]
Ọ̀wọ́ ẹ̀yà ní ìpínlẹ̀ Ondo kún fún ọ̀pọ̀ ẹ̀yà Yoruba ìdá ọ̀wọ́ ti Idanre, Akoko, Akure, Ikale, Ilaje, Ondo, àti àwọn èèyàn Owo. Ará Ijaw, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn Apoi àti Arogbo ń gbé ní gúúsù-ìlà-oòrùn létí omi tó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Edo. Díẹ̀ nínú àwọn èrò tí wọ́n ń sọ ẹ̀ka èdè Yorùbá tí ó jọ èdè Ife ní Oke-Igbo tí ó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Osun.[20] Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èrò yìí jẹ́ ẹlẹ́siǹ Kììtẹ́nì; tí àwọn diẹ jẹ́ ẹlẹ́siǹ Mùsùlùmí àti àbàlàyé.[21][22]
Àtòpọ̀ àwọn èdè ní ìpínlẹ̀ Ondo látọwọ́ àwọn ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀:[23]
LGA | Languages |
---|---|
Akoko South East | Yoruba (Ao), Uhuami, Ukue |
Akoko South West | Yoruba (Akoko, Ekiti) |
Akoko North East | Yoruba (Akoko), Arigidi, Ayere |
Akoko North West | Yoruba (Akoko, Ekiti), Abesabesi, Arigidi, Ayere |
Akure North | Yoruba (Ekiti) |
Akure South | Yoruba (Ekiti) |
Ese-Odo | Yoruba (Apoi), Izon |
Idanre | Yoruba (Ondo, Ekiti) |
Ifedore | Yoruba (Ekiti) |
Ilaje | Yoruba (Ilaje) |
Ile Oluji/Okeigbo | Yoruba (Ondo, Ife) |
Irele | Yoruba (Ikale) |
Odigbo | Yoruba (Ikale, Ondo) |
Okitipupa | Yoruba (Ikale) |
Ondo East | Yoruba (Ondo) |
Ondo West | Yoruba (Ondo) |
Ose | Yoruba (Ogho, Ao), Owan (Ora) |
Owo | Yoruba (Ogho) |
Àwọn ohun wọ̀nyí ni ohun àlùmọ́nì ti wọ́n ní ìpínlẹ̀ Ondo:[24]
Local government area | Male | Female | Total |
---|---|---|---|
Akoko North-West | 108,057 | 105,735 | 213,792 |
Akoko North-East | 93,060 | 82,349 | 175,409 |
Akoko South-East | 41,995 | 40,431 | 82,426 |
Akoko South-West | 123,979 | 105,507 | 229,486 |
Ose | 73,395 | 71,506 | 144,901 |
Owo | 110,429 | 108,457 | 218,886 |
Akure North | 66,878 | 64,709 | 131,587 |
Akure South | 175,495 | 177,716 | 353,211 |
Ifedore | 92,014 | 84,313 | 176,327 |
Ile Oluji | 87,505 | 85,365 | 172,870 |
Ondo West | 139,400 | 144,272 | 283,672 |
Ondo East | 38,032 | 36,726 | 74,758 |
Idanre | 66,996 | 62,028 | 129,024 |
Odigbo | 114,814 | 115,537 | 230,351 |
Okitipupa | 120,626 | 112,939 | 233,565 |
Irele | 75,636 | 69,530 | 145,166 |
Ese Odo | 78,100 | 76,878 | 154,978 |
Ilaje | 154,852 | 135,763 | 290,615 |
Total | 1,761,263 | 1,679,761 | 3,441,024 |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.