Olusegun Mimiko jẹ olósèlú ọmọ ilẹ̀ Nàíjíríà àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òǹdó láti ọdún 2009 dé ọdún 2017. Ọjọ́ kẹ́ta oṣù Ọ̀wàwà ní wọ́n bí Olúṣẹ́gun Rahman Mimiko ọdún 1954. Ó jẹ́ olùdíje fún ipò sẹ́nẹ́tọ̀ ní agbègbè àárín gbìngbùn Òǹdó lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Zenith Labour Party nínú ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.[1]

Quick Facts Gomina Ipinle Ondo, Asíwájú ...
Olusegun Rahman Mimiko
Gomina Ipinle Ondo
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
24 February 2009
AsíwájúOlusegun Agagu
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí3 Oṣù Kẹ̀wá 1954 (1954-10-03) (ọmọ ọdún 70)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúLabour Party
(Àwọn) olólùfẹ́Olukemi Mimiko
Occupationphysician
Close

Olúṣẹ́gun ní gómìnà alágbádá ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà láti 2009 sí 1017. Mimiko ti fi ìgbà kan jẹ́ mínísítà ìjọba àpapọ̀ fún ilé àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, sẹ́kétírì sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ gómìnà àkọ́kọ́ tí ó jẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour party ní orílẹ̀-èdè Nàíjírià. Bákannáà ni ó jẹ komíṣọ́nà léèmejì fún ètò ìlera.

Ìlú Ondo ní ìpínlẹ̀ Ondo, apá Ìwọ̀-oòrù̀n gúsù orílẹ̀-èdè Nigeria. Àti kékeré ni ó ti nífẹ̀ẹ́ si òṣèlú, èyí sì farahàn nínú àwọn ipò tí ó dì mú nìgbà tí oh wà ní ilé-ìwé àwọn oníṣègùn òyìnbó ní University of Ife (tó di Obafemi Awolowo University lónìí).

Lẹ́yìn ìgbà tí ó parí agùnbánirọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ oníṣègùn òyìnbó. Ní ọdún 1985, ó dá ilé-iṣẹ́ MONA MEDICLINIC sílẹ̀ ní Ondo èyí ti ó dúró gẹ́gẹ́ bí ohun ètò ọ̀fẹ́ fún àgbègbè náà.[2]

Itokasi

Wikiwand in your browser!

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.

Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.

Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.