From Wikipedia, the free encyclopedia
Mosunmola Abudu, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Mo Abudu, tí ó sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ògbóǹtarìgì agbóhùnsáfẹ́fẹ́, ẹlẹ́yinjú àánú, onímọ̀ràn ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́ àti ẹni tí a mọ̀ mọ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́.[1][2] Forbes fi Mo Abdul hàn gẹ́gẹ́ bíi obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó lọ́lá jù lọ ni.[3][4]
Mo Abudu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 11 Oṣù Kẹ̀sán 1964 London, United Kingdom |
Ẹ̀kọ́ | Ridgeway School MidKent College West Kent College University of Westminster |
Iṣẹ́ | Media proprietor |
Website | ebonylifetv.com |
A bí Abudu sí Hammersmith ní apá Ìwọ̀-oòrùn ní London.[1] UK ni ó ti ṣe èwe. Ó sì lọ sí Ridgeway School, MidKent College àti West Kent College. Ó gboyè Master's degree nínú Human Resource Management ní London.
Ní ọdún 2006,Abudu bẹ̀rẹ̀ EbonyLife TV,[5][6][7] ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ó tàn ká orílẹ̀-èdè tó ju ọkàndínláàádọ́ta lọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti ní UK àti Caribbean.[8] Ó jẹ́ ètò kan lábẹ́ Media and Entertainment City Africa (MEC Africa). EbonyLife TV wà ní Tinapa Resort ní Calabar, Ìpínlẹ̀ Cross Rivers, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ní ọdún 2018, Sony Pictures Television (SPT) kéde àṣẹ̀ṣẹ̀yanjú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ọlọ́dún mẹ́ta pẹ̀lú EbonyLife TV tí ó máa ní ṣe pẹ̀lú gbígbé fíìmù The Dahomey Warriors jáde.[9]
Abudu dá EbonyLife Films sílẹ̀. Àkọ́lé fíìmù tí ó kọ́kọ́ gbé jáde ni Fifty. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ELFIKE ní ọdún 2016 láti gbé fíìmù The Wedding Party jáde.[10]
Abudu jẹ́ olóòtú àti ẹni tó gbé ètò "Moments with Mo" kalẹ̀ tí ó jẹ́ ètò ojoojúmọ́ àkọ́kọ́ tí ó hàn káàkiri ilẹ̀ Adúláwọ̀ lórí afẹ́fẹ́.[11][12]
Ní ọdún kẹwàá ọdún 2009, a ti rí tó igba ìgbà tí ètò tí ó gbé sórí afẹ́fẹ́ hàn lórí afẹ́fẹ́. Àwọn ètò orí afẹ́fẹ́ náà máa ń dá lé lórí ìgbésí ayé ẹ̀dá, ètò-ìlera, àṣà, ètò-òṣèlú, eré-ìdárayá, ìṣe, orin àti ọ̀rọ̀ lórí ìgbéyàwó láàárín ẹ̀yà méjì. Wọ́n ti gbé àwọn olókìkí èèyàn lóríṣiríṣi, Ààrẹ orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn tó lórúko sórí ètò náà.[1][13]
Abudu jẹ́ olùdásílẹ̀ àti ẹni tó gbé ètò The Debaters jáde. Ó jẹ́ ètò tí Guaranty Trust Bank ń ṣàkóso nípa ètò ìṣúná. Ọjọ́ kẹta oṣù kẹwàá ọdún 2009 ni wọ́n dá a sílẹ̀. Ètò náà dá lé lórí "fífún ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ohùn kan" nípa gbígbé ọ̀rọ̀ sísọ lárugẹ.[14]
Forbes Africa fi Abudu hàn bíi obìnrin Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ láti ni Pan-Africa TV channel ní ọdún 2013.[15][16] Wọ́n kà á mọ́ ọkàn lára àwọn obìnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó lọ́lá jù lọ lórí Global TV láti owó oníròyìn Hollywood ní ọdún 2013.[17] and received the Entrepreneur of the Year award by Women Werk in New York (2014).[18] Ní ọdún 2014, Babcock University dá a lọ́lá pẹ̀lú Honorary Doctor nínú Humane Letters.[19] Ní ọdún 2019, wọ́n dá a lọ́lá pẹ̀lú Médailles d'Honneur ti MIPTV 2019 ní Cannes, ìlú France. Èyí sì jẹ́ kó jẹ́ obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tó gba àmì ẹ̀yẹ náà.[20] Bákan náà, wọ́n kà á mọ́ ọkàn lára ọgọ́rùn-ún obìnrin tí ó lọ́lá jù lọ lórí 2020 Powerlist ní UK láti ilẹ̀ Adúláwọ̀.[21]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.