Ìpínlẹ̀ Ògùn
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà / From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da Ìpínlẹ̀ Ògùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 1976. Ìpínlẹ̀ Ògùn fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Èkó lápá Gúúsù, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lápá Àríwá, Ìpínlẹ̀ Òndó àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin lápá Ìwọ̀-Oòrùn. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Ọmọọba Dapo Abiodun tí wọ́n dìbò yàn-án wọlé lọ́dún 2019. Abẹ́òkúta ni olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìlú tí ó ní ọ̀pọ̀ olùgbé jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà. Méjì lára àwọn ìlú mìíràn tí ó ṣe pàtàkì ni Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ìjẹ̀bú-Òde, olú-ìlú ọba aládé tí Ìjẹ̀bú Kingdom fún ìgbà kàn rí àti Sagamu, ìlú tí ń ṣe aṣáájú níbi ká gbin obì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tó ń ṣe agbátẹrù ètò ọrọ̀ ajé tó múnádóko.
Ìpínlẹ̀ Ògùn | |||
---|---|---|---|
Àwòrán agbègbè mọ́ṣáláṣí kan ní Gbagura ní ìlú Abẹ́òkuta, ní ìpínlè Ògùn | |||
| |||
Nickname(s): | |||
Location of Ogun State in Nigeria | |||
Coordinates: 7°00′N 3°35′E | |||
Country | Nigeria | ||
Date created | 3 February 1976 | ||
Capital | Abeokuta | ||
Government | |||
• Body | Government of Ogun State | ||
• Governor | Dapo Abiodun (APC) | ||
• Deputy Governor | Noimot Salako-Oyedele (APC) | ||
• Legislature | Ogun State House of Assembly | ||
• Senators | C: Ibikunle Amosun (APC) E: Ramoni Olalekan Mustapha (APC) W: Tolu Odebiyi (APC) | ||
• Representatives | List | ||
Area | |||
• Total | 16,980.55 km2 (6,556.23 sq mi) | ||
Area rank | 24th of 36 | ||
Population (2006 census) | |||
• Total | 3,751,140 | ||
• Rank | 16 of 36 | ||
• Density | 220/km2 (570/sq mi) | ||
Demonym(s) | Ogun | ||
GDP | |||
• Year | 2007 | ||
• Total | $10.47 billion[1] | ||
• Per capita | $2,740[1] | ||
Time zone | UTC+01 (WAT) | ||
postal code | 110001 | ||
ISO 3166 code | NG-OG | ||
HDI (2018) | 0.662[2] medium · 2nd of 37 |