![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/9/9d/Nigeria_sm02.gif/640px-Nigeria_sm02.gif&w=640&q=50)
Ìwó
From Wikipedia, the free encyclopedia
Iwo jẹ́ ìlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ará Ìwó, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Yorùbá mìíràn ṣẹ̀ wá láti Ile-Ife, tí wọ́n ṣí kúrò ní sẹ́ńtúrì kọkànlá, gẹ́gẹ́ bí Alademomi kenyon àti Prince Adelegan Adegbola (2009) ṣe sọ.[1][2] Ìlú náà fìgbà kan wà lára ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọ́n wá padà yọ kúrò, tó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ìlú tó ṣe pàtàkí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Iwo Ìwó Odíderé | |||
---|---|---|---|
LGA and city | |||
Nickname(s): Iwo Olodo Oba | |||
Motto(s): Iwo Olodo Oba, Iwo Ateni Gbola Ateni Gbore. | |||
Coordinates: 7°38′N 4°11′E | |||
Country | ![]() | ||
State | Osun State | ||
Founded by | Oluwo | ||
Government | |||
• Oluwo of Iwo | HRM Oba Abdulrosheed Akanbi | ||
• Local Government Chairman | Raji Kamoru Abiodun | ||
Area | |||
• Total | 7,543 km2 (2,912 sq mi) | ||
Population (2006 Census) | |||
• Total | 191,377 | ||
(central city/Local Government) | |||
Time zone | UTC+1 | ||
3-digit postal code prefix | 232 | ||
ISO 3166 code | NG.OS.IO | ||
National language | Yorùbá | ||
|
Àwọn Ọba tí wọ́n ti jọba lórí ìlú yìí ju ọgbọ̀n lọ, lábẹ́ Oluwo ti ìlú Ìwó, HRM Oba Abdulrosheed Akanbi, gẹ́gẹ́ bí i aláṣẹ ìlú náà. Ìlú yìí tóbi ní ìwọ̀n 245 km2, pẹ̀lú iye ènìyàn tó tó 191,348. Èyí sì jẹ́ ìlú tó ní ènìyàn tó pọ̀ jù lọ ní àsìkò ìka iye ènìyàn tó wáyé ní ọdún 2006, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn tó wà níbẹ̀ ni; agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Aiyedire, tó tóbi pẹ̀lú ìwọ̀n 265.783 km2, tó sì ní iye ènìyàn 76,309, àti agbègbè ìjọba ìbílè Ola-Oluwa, tó tóbi pẹ̀lú ìwọ̀n 332.117 km2, tí ó sì ni iye ènìyàn 76,227. Olú-ìlú àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yìí wà ní; ààrin gbùngùn Iwo (Central), Iwo; Aiyedire, Ile Ogbo; àti Ola-Oluwa, Bode-Osi. Iwo ti ní àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin si, àwọn ni: Iwo East, Olomowewe; Iwo West, Agberire; Ọla Oluwa South East, Ilemowu; Ayedire South East, Oluponna.