Ilé-Ifẹ̀
ìlú pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá ní Nàìjíríà / From Wikipedia, the free encyclopedia
Ifẹ̀ (Yorùbá: Ifẹ̀, tabi Ilé-Ifẹ̀) jẹ́ orírun gbogbo ọmọ Oòduà ní ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé-Ifẹ̀ wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[2] Ifẹ̀ sí ìlú Ìpínlẹ̀ Èkó je kilomita igba o le mejidinlogun (218) [3] tí àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé ibẹ̀ lápapọ̀ jẹ́ 509,813 níye. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, Ilé-Ifẹ̀ ni wọ́n dá sílẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè nígbà tí ó pàṣẹ fún Ọbàtálá kí ó wá láti dá ayé kí ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṇ́ fẹ̀ láti ibẹ̀ lọ káàkiri àgbáyé; ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe Ilé-Ifẹ̀ ní Ifẹ̀ Oòyè, ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wáyé. Àmọ́, Ifẹ̀ yí ni Ọbàtálá pàdánù rẹ̀ sọ́wó Odùduwà Atẹ̀wọ̀nrọ̀, èyí ni ó fàá tí fàá ká ja ṣe wà láàrín àwọn méjèèjì.[4] Odùduwà ni ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba ní Ifẹ̀, ní èyí tí àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo náà sì di adarí àti olórí ìlú ní ẹlẹ́ka-ò-jẹ̀ka ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí káàkiri orílẹ̀ Yorùbá lóní.[5] Gẹ́gẹ́ bí a ti kàá nínú ìtàn, Ọọ̀ni àkọ́kọ́ tí yóò kọ́kọ́ jẹ ní Ifẹ̀ ni ó jẹ́ ọmọ bíbí inú Odùduwà tí ó jẹ́ ọ̀kànlélógójì òrìṣà fúnra rẹ̀, nígbà tí Ọọ̀ni tí ó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyí jẹ́ Ọọ̀ni Adéyẹyè Ẹnìtàn Ògúnwùsì Ọ̀jájá Kejì(II) tí wọ́n jẹ ní ọdún 2015. Bákan náà ni Ilé-Ifẹ̀ ní ọ̀kànlélúgba òrìṣà tí wọ́n ma ń bọ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan yípo ọdún.[6] [7]
Ilé-Ifẹ̀ Ifè Oòyè | |
---|---|
Fọ́nrán àwòrán èdè Ilé-Ifẹ̀ | |
Coordinates: 7°28′N 4°34′E | |
Country | Nigeria |
State | Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun |
Government | |
• Ọọ̀ni | Ọ̀jájá II |
• LGA Chairman, Ife Central | Ọ́ládosù Olúbísí |
• LGA Chairman, Ife North | Lánre Ògúnyímiká |
• LGA Chairman, Ife South | Timothy Fáyẹmí |
• LGA Chairman, Ife East | Tajudeen Lawal |
Area | |
• Total | 1,791 km2 (692 sq mi) |
Population (2006)[1] | |
• Total | 509,035 |
• Density | 280/km2 (740/sq mi) |
Climate | Aw |
Àpapọ̀ iye oníbùgbé |
---|
~ 755,260 |
Regions with significant populations |
Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun - 755,260 (2011) · Ife Central: 196,220 · Ife East: 221,340 · Ife South: 157,830 · Ife North: 179,870 |
Ilé-Ifè ìlú ńlá tí òkìkí rẹ̀ kàn jákè-jádò àgbáyé fún àwọn Iṣẹ́ ọnà wọn bíi ère orí Odùduwà àti àwọn ohun ọnà míràn tí wọ́n lààmì-laaka ní ǹkan bí ọdún 1200 àti 1400 A.D sẹ́yìn.[7]