Steve Gukas
From Wikipedia, the free encyclopedia
Steve Gukas jẹ́ ẹni tó ń ṣe fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà olùdarí fíìmù àti àṣagbátẹrù fíìmù tó gbàgbọ́ pé àwọn fíìmù tí à ń gbé jáde gbọdọ̀ rí ojútùú sí àwọn ìṣẹ̀lẹ́ inú àwùjọ.[1][2]
Steve Gukas | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Filmmaker, Film director |
Gbajúmọ̀ fún | 93 Days (2016) • A Place in the Stars (2014) |
Ètò èkọ́ rẹ̀
Gukas kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Television Production ní NTA TV College ní Jos. Ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa Theatre Arts ní University of Jos àti nípa Film production ní London Film School, United Kingdom.
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
Ó fìgbà kan jẹ́ olùdarí ọ̀kan lára àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò ní Nàìjíríà, ìyẹn WE FM.[3]
Ní ọdún 2002, ó darí fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Keeping Faith". Ní ọdún 2007, ó ṣàgbéjáde fíìmù "Namibia: The Struggle for Liberation", èyí tí òṣèrẹ́kùnrin ilẹ̀ America kan kópa nínú rẹ̀, ìyẹn Danny Glover;[4] fíìmù yìí jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́.[5]
Ní ọdún 2014, wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù kan tó jẹ́ darí, tó sì ṣagbátẹrù, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́, "A Place in the Stars" . Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Segun Arinze, Dejumo Lewis, Matilda Obaseki, Gideon Okeke, Yemi Blaq àti Femi Branch. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 2015, fíìmù náà gba amì-ẹ̀yẹ Africa Magic Viewers Choice Awards (AMVCA), gẹ́gẹ́ bí i fíìmù tó dára jù lọ.[4]
Ní ọdún 2016, ó darí fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "93 Days", tó dá lórí oníṣègùn ilẹ̀ Nàìjíríà kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dr. Stella Ameyo Adadevoh, tó ṣiṣẹ́ takuntakun láti kojú àrùn Ebola tó bẹ̀ sílẹ̀ sí Nàìjíríà ní ọdún 2014. Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Bimbo Akintola, Danny Glover, Seun Ajayi, Keppy Ekpeyong àti Bimbo Manuel.[6][7][8][9][10]
Òun náà ló ṣàgbéjáde fíìmù "Keeping The Faith" àti "Mr. Johnson".[4]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
Ọdún | Àkọ́lé | Ipa | Notes |
---|---|---|---|
2019 | Living in Bondage: Breaking Free | co-producer | |
2016 | 93 Days | director | |
2014 | A Place in the Stars | director •
co-producer |
|
2007 | Namibia: The Struggle for Liberation | producer | |
2002 | Keeping Faith | director |
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.