Aare orile-ede Naijiria tele From Wikipedia, the free encyclopedia
Muhammadu Buhari (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ ketàdínlógún, Oṣù Kejìlá Odún 1942) olóṣèlú tí ó jẹ́ Ààrẹ orílè-èdè Nàíjíríà láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2023.[5][6] Ó lo ṣáà àkọ́kọ́ rẹ̀ láàrin odún 2015 sí 2019 àti kejì láàrin ọdún 2019 sí 2023[7]. Buhari tí fìgbà kan jẹ́ ogágun Méjọ̀ Gẹ́nẹ́rà àti pé ó j̣e olórí orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lati 31st Oṣù kejìlá odún 1983 sí Oṣù kẹjó odún 1985, léyìn tí ó fi kúùpù ológun gbàjọba.[8][9]
His Excellency Muhammadu Buhari | |
---|---|
Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà 7k & 15k | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 29 Oṣù Kàrún 2015 | |
Vice President | Yemi Osinbajo |
Asíwájú | Goodluck Jonathan |
Chair of the Supreme Military Council | |
In office 31 Oṣù Kejìlá 1983 – 27 Oṣù Kẹjọ 1985 | |
Vice President | Tunde Idiagbon (Chief of Staff) |
Asíwájú | Shehu Shagari (President) |
Arọ́pò | Ibrahim Babangida (Chair of the Armed Forces Ruling Council) |
Ijoba Ijoba ti Awọn Ọkọ Ẹrọ | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 11 Kọkànlá Oṣù 2015 | |
Asíwájú | Diezani Allison-Madueke |
Gómínà ìpínlẹ̀ Bọ̀nú | |
In office 3 Oṣù Kejì 1976 – 15 Oṣù Kẹta 1976 | |
Asíwájú | Position established |
Arọ́pò | Mustapha Amin |
Governor of the Northeastern State | |
In office 1 Oṣù Kẹjọ 1975 – 3 Oṣù Kejì1976 | |
Asíwájú | Musa Usman |
Arọ́pò | Position abolished |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kejìlá 1942 Daura, Northern Region, Nigeria[1][2] (now Daura, Katsina State, Nigeria) |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Safinatu Yusuf (m. 1971; div. 1988) |
Àwọn ọmọ | 10 |
Alma mater | Nigerian Military Training College Mons Officer Cadet School U.S. Army War College |
Website | Official website |
Military service | |
Nickname(s) | Baba go slow[3][4] |
Allegiance | Nàìjíríà |
Branch/service | Adigun Nàìjíríà |
Years of service | 1961–1985 |
Rank | Major General |
*Yemi Osinbajo served as Acting President from 19 January 2017 – 13 March 2017 and 7 May 2017 – 21 August 2017 while Buhari received medical treatment. |
A bí Muhammadu Buhari sí ìdílé Fulani ní ọjọ 17 Kejìlá 1942, ní Daura, Ìpínlè Katsina[10], baba rẹ ni Hardo Adamu, ẹni tí ó jẹ́ olori Fulani, orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Zulaihat, ẹni tí ó Hausa.[11][12] Òun ni ọmọ kẹtalelogun bàbá rẹ̀. Ìyá Buhari ni ó tọ dàgbà, bàbá rẹ̀ fi ayé sílè nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rinrin[13].
Buhari dara pò mó Nigerian Military Training College (NMTC) ní ọdun 1962, ó jẹ́ omo odun kan dínlógún nígbà náà.[14] Ní oṣù kejì ọdún 1964, a yí orúkọ ilé-ìwé ológun náà padà sí Nigerian Defence Academy (NDA).
Ní àárín 1962 sí 1963, Buhari kó nípa ìmò ogun ní Mons Officer Cadet School ní ìlú Aldershot, England.[15] Ní oṣù kínní ọdún 1963, nígbà tí Buhari jẹ́ ọmọ ọdún ogún, a sọ́ di lieutenanti kejì.
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.