Ìpínlẹ̀ Ògùn
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da Ìpínlẹ̀ Ògùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 1976. Ìpínlẹ̀ Ògùn fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Èkó lápá Gúúsù, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lápá Àríwá, Ìpínlẹ̀ Òndó àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin lápá Ìwọ̀-Oòrùn. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Ọmọọba Dapo Abiodun tí wọ́n dìbò yàn-án wọlé lọ́dún 2019 fun ìgbà àkokò re, wón si tun dibò yàn án nì èkeji nì òdún 2023. Abẹ́òkúta ni olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìlú tí ó ní ọ̀pọ̀ olùgbé jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà. Méjì lára àwọn ìlú mìíràn tí ó ṣe pàtàkì ni Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ìjẹ̀bú-Òde, olú-ìlú ọba aládé tí Ìjẹ̀bú Kingdom fún ìgbà kàn rí àti Sagamu, ìlú tí ń ṣe aṣáájú níbi ká gbin obì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tó ń ṣe agbátẹrù ètò ọrọ̀ ajé tó múnádóko. Orúkọ ìnagijẹ ìpìnlẹ̀ Ògùn ni the Gateway State.
Ìpínlẹ̀ Ògùn | |||
---|---|---|---|
Àwòrán agbègbè mọ́ṣáláṣí kan ní Gbagura ní ìlú Abẹ́òkuta, ní ìpínlè Ògùn | |||
| |||
Nickname(s): | |||
Location of Ogun State in Nigeria | |||
Coordinates: 7°00′N 3°35′E | |||
Country | Nigeria | ||
Date created | 3 February 1976 | ||
Capital | Abeokuta | ||
Government | |||
• Body | Government of Ogun State | ||
• Governor | Dapo Abiodun (APC) | ||
• Deputy Governor | Noimot Salako-Oyedele (APC) | ||
• Legislature | Ogun State House of Assembly | ||
• Senators | C: Ibikunle Amosun (APC) E: Ramoni Olalekan Mustapha (APC) W: Tolu Odebiyi (APC) | ||
• Representatives | List | ||
Area | |||
• Total | 16,980.55 km2 (6,556.23 sq mi) | ||
Area rank | 24th of 36 | ||
Population (2006 census) | |||
• Total | 3,751,140 | ||
• Rank | 16 of 36 | ||
• Density | 220/km2 (570/sq mi) | ||
Demonym(s) | Ogun | ||
GDP | |||
• Year | 2007 | ||
• Total | $10.47 billion[1] | ||
• Per capita | $2,740[1] | ||
Time zone | UTC+01 (WAT) | ||
postal code | 110001 | ||
ISO 3166 code | NG-OG | ||
HDI (2018) | 0.662[2] medium · 2nd of 37 |
Ìjọba ìbílẹ̀ ogún ló wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, àwọn sì ni:
Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilé-ìwé ìjọba àpapọ̀ mẹ́ta, àwọn ni; Federal Government Girls' College, Sagamu [3] àti Federal Government College, Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odogbolu[4] àti Federal Science and Technical College, Ijebu-Imushin.[5]
Ìpínlẹ̀ náà ní Yunifásitì ìjọba àpapọ̀ kan, tí ń ṣe; Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB[6]) àti college of education tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ kan, tí ń ṣe FCE Osiele (méjèèjì wà ní Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odeda), college of education kan, tó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ náà, tí wọ́n fi sọrí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ti ṣaláìsì báyìí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Augustus Taiwo Solarin tí wọ́n dá kalè ní ọdún 1994, tí wọ́n pè ní Tai Solarin University of Education#(TASCE[7]. Ó tún ní Polytechnic kan ní Ilaro, tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀, tí wọ́n fi sọrí oníṣòwò ilẹ̀ Nàìjíríà àti olúborí ìdíje òṣèlú ti June 12, 1993, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Basorun Moshood Kasimawo Olawale Abiola, tí wọ́n pè ní Moshood Abiola Polytechnic (MAPOLY[8]), tí ó fìgbà kan jẹ́ Ogun State Polytechnic, Ojere, Abeokuta. Àwọn mìíràn ni Another Gateway Polytechnic Saapade,[9] Remo (GAPOSA), Abraham Adesanya Polytechnic[9] Ijebu-Igbo (Aapoly) (tí ó fìgbà kan jẹ́ 'The Polytechnic Ijebu-Igbo) tí wọ́n fi sọrí Chief Abraham Aderibigbe Adesanya, tó jẹ́ olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà, agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn. Yunifásitì ti ìjọba méjì tó ń ṣe: Olabisi Onabanjo University, Ago Iwoye (tí ó fígbà kan jẹ́ Ogun State University), àti Tai Solarin University of Education (TASUED[10]) Ijebu Ode.
Ìpínlẹ̀ Ògùn ní Yunifásitì mẹ́sàn-án lápaapọ̀ tó ti wà ní ìforúkọsílẹ̀, tó sì pọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lára wọn ni Yunifásitì aládàáni márùn-ún:[11] Chrisland University, Abeokuta Bells University of Technology ní Ota, Covenant University àti Babcock University ní Ilisan-Remo, tó jẹ́ Yunifásitì aládàáni àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìpínlẹ̀ náà ní ilé-ìwòsàn tó jẹ́ ti ìjọba méjì, tí ń ṣe: Federal Medical Center ní ìlú Abeokuta, àti Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital ní Sagamu.
Gbàdede National Youth Service Corps (NYSC) wà ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Sagamu, ní ìpínlẹ̀ náà.
Ìpínlẹ̀ Ògún jẹ́ dídílẹ̀ láti ọwọ́ ìjọba Murtala/Ọbásanjọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejì, ọdún 1976 látara níhàa Ìwọ̀-Oòrùn àtijọ́. Wọ́n sọ ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn odò Ògùn, tí odò náà ṣàn káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti Àríwá lọ sí Gúúsù. Ìpínlẹ̀ náà ní àyíká ìgbìmọ̀ ìjọba agbègbè ogún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọwọ́ ajẹmọ́-ìran mẹ́fà tó tóbi, àwọn náà ni: Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Rẹ́mo, Ẹgbádọ̀, Àwọrí àti Ègùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn kékeré mìíràn wà bí Ìkálẹ̀, Kẹ́tu, Ohori àti Anago.[16] Ìwé- ìpamọ́ jẹ́ẹ̀rí pé ìpínlẹ̀ yìí ló ní Fáṣítì Àdáni àti ilé-ìwé gíga ní Nàìjíríà àti ìpínlẹ̀ tó ní Fáṣítì ìpínlẹ̀ ara rẹ̀ méjì ni Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ògùn tún jẹ́ ilé fún Fáṣítì fún Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ àti ìgbẹ̀yìn.[17] [18]
Ìpínlẹ̀ Ògùn tí pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ìjọba ní Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn. Gbogbo àwọn ara Gúúsù Ìwọ̀-Oòrùn tó ti jẹ Ààrẹ tàbí olórí ìpínlẹ̀ fún ìlú wá láti ìpínlẹ̀ Ògùn (Ọbásanjọ́, Shónẹ́kàn) wọ́n gba oríyìn láti ìpínlẹ̀ Ògùn. Olóyè Jeremiah Ọbáfẹ́mi Àwọ́lọ́wọ̀, Olórí àkọ́kọ́ fún Agbègbè Ìwọ̀-oòrùn, ó dẹ̀ jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn ará Ìjẹ̀bú ní ìpínlè yìí ni àwọn Yóò á àkọ́kọ́ tó nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Europe ní ṣẹ́ńtíúrì kẹrìnlá. Àwọn ènìyàn náà tún gbà wí pé àwọn ni ẹ̀yà Yoòbá tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ma lọ owó tí a mọ̀ sí owó-Ẹyọ, tí ó jẹ́ àtawọ́gbà ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá kí wọ́n tí rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ìsì nígbà tí àwọn Europe dẹ́.[19]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.