Remove ads
From Wikipedia, the free encyclopedia
Wón bi Olatunji-Bello sí agbègbè Ogbowo ní Ìdúmọtà, ní ìpínlẹ̀ Èkó nínu ìwọ̀ oòrùn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ orílẹ̀ èdè Naigiria ní ọjọ́ kẹta-lélógún oṣù kẹ́rin, ọdún 1964. O lọ si Ile-iwe Girama Ọ̀dọ́mọbìnrin Anglican ni Surulere láàárín ọdun 1970 àti 1974 àti Ile-iwe gíga àwọn ọmọbìnrin mẹtodist, ni agbègbè Yaba fún Ilé-ìwé Àtẹ̀lẹ̀ gíga láàárín 1974 àti 1979. Fún ètò-ẹ̀kọ́ gíga, ó lọ Lagos State College of Science and Technology, Ile iwe giga ti ilu Ibadan, níbi tí ó ti gba oyè ní fisiọ́lọ́jì ní ọdún 1985. Ó gba oyè nípa Fisiọ́lọ́jì láti University of Lagos ni 1987. [1] ó tún lọ sí University of Texas ní San Antonio, Ile-iṣẹ Imọ Ilera, San Antonio laarin 1994 ati 1998. [2]
Ibiyemi Olatunji-Bello | |
---|---|
Alakoso ẹlẹkẹsàán ti Fásitì Ìpínlẹ̀ Eko | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga ọjọ eirndinlogun, oṣu kẹsan ọdun 2021 | |
Asíwájú | Olanrewaju Fagbohun |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 23 Oṣù Kẹrin 1964 Ipinle Eko, |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olatunji Bello |
Website | https://ibiyemiolatunjibello.com |
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ olùkọ́ ní ile iwe giga ti Ìṣègùn, fasiti ti ilu Èkó. ó sì gba ipò rẹ̀, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìṣègùn ní Lagos State University College of Medicine ní ọdún 2007. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì fásitì ìpínlẹ̀ Èkó (LASU) ní ọdún 2008. Bakan naa lo tun je igbakeji kanselu fasiti ipinle Eko ti a mo si LASU ko to di pe Ojogbon Ibiyemi Olatunji-Bello ti yan gege bi Igbakeji Alakoso 9th ti Eko State University (LASU). Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú The Nation, ó mẹ́nu kan pé òun di igbákejì ọ̀gá àgbà nítorí pé ó jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run yàn fún òun. [3]
Iyaafin Olatunji-Bello ni iyawo komisanna Bello Olutunji ti o jẹ kọmiṣanna fun ayika ati awọn orisun omi ni Ipinle Eko. Iyaafin Bello-Olutunji ni ọmọ mẹta. [4] [5]
Olatunji-Bello ti Àami ẹ̀yẹ àṣeyọri Awọn obinrin ni orilẹ-ede Naijiria ni ẹka ti O tayọ julọ ni Ẹkọ Ile-ẹkọ giga. [6]
Olatunji-Bello tun wa ninu atokọ ti "Obinrin Naijiria Ọdọọdun: 100 Obinrin asiwaju" fun ọdun 2022. [7]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.