Remove ads
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà láàárin àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì náà, ó pọ̀ níye ó sì kéré ní ààyè. Ó sopọ̀ mọ́ gúúsù nípasẹ̀ àwọn ìgbèríko Benin àti sí ìwọ̀-oòrùn nípasẹ̀ ààlà òkèèrè pẹ̀lu Ìlu Benin, Ìpínlẹ̀ Èkó ń pín àwọn ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ogun sí ìlà-oòrùn àti àríwá ní èyí tí ó mu jé ìpńilẹ̀ kan ṣoṣo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó pín ààlà pẹ̀lú ìpínlẹ̀ kan péré. Orúkọ fún ìlú Èkó — Ìlú tí ó pọ̀ jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ — wọ́n dá ìpínlẹ̀ náà látara agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn tí ó sì jẹ́ olú-ìlú tẹ́lèrí ní ọjọ́ kẹ́tadínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún, ọdún 1967.[4][5]
Ìpínlẹ̀ Èkó | ||
---|---|---|
| ||
Location of Lagos State in Nigeria | ||
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà | |
Ọjọ́ ìdásílẹ̀ | May 27, 1967 | |
Olùìlú | Ikeja | |
Government | ||
• Gómìnà[1] | Babájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú (APC) | |
• Àwọn alàgbà |
| |
• Àwọn aṣojú | Àkójọ | |
Area | ||
• Total | 3,475.1 km2 (1,341.7 sq mi) | |
Population (2006 Census)[2] | ||
• Total | 9,013,534 | |
• Density | 2,600/km2 (6,700/sq mi) | |
GIO (PPP) | ||
• Ọdún | 2007 | |
• Total | $33.68 billion[3] | |
• Per capita | $3,649[3] | |
Time zone | UTC+01 (WAT) | |
ISO 3166 code | NG-LA | |
Website | lagosstate.gov.ng |
Gégẹ́ bí ìtọ́ka agbègbè, Ìpínlẹ̀ Èkó jé ilẹ̀ omi tí ìdá-mẹ́rin rẹ̀ dín ní díẹ̀ kúnfún òṣà, itọ́ àti àwọn odò.[6] Èyí tí ó fẹ̀ jù nínú àwọn omi wọ̀nyí ni ọ̀sà Èkó àti Lekki nínú ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú odò Ogun àti Osun tí ó ń sàn wọnú wọn. Àwọn omi yòó kù jẹ́ itọ́ tí ó ń sàn kiri ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀nà ìrìnàjò pàtàkì fún àwọn èèyàn àti àwọn ọjà. Nítòsí etí omi, ìpínlẹ̀ yìí bákan náà ṣàkónú àwọn onírúnrú ohun ọ̀gbìn, ẹranko àti ẹranmi gẹ́gẹ́ bí ẹjá ṣe wà náà ni àwọn ẹranmi ilẹ̀ adúláwọ̀ àti àwọn ọ̀ọ̀nì.[7][8]
Ìpínlẹ̀ Èkó ti jé ibùgbé fún ọdún tó ti pẹ́ nípasẹ̀ àwon ọ̀wọ́ onírúnrú ẹ̀yà onílùú, nípàtàkì awọn ọmọ Yoruba ni wọ́n ń gbé káàkiri ìpínlẹ̀ náà àmọ́ àwọn èèyan Ewe àti Ogu náà ń gbé ibi tí o nasẹ̀ lápá ìwọ̀ oòrùn.
Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí síṣí lọ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn láti bíi ọ̀rúndún sẹ́yìn, ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú ti ní èrò tó pọ̀ tí wọn kìí ṣe àwọn ọ̀wọ́ ẹ̀yà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú Edo, Fulani, Hausa, Igbo, Ijaw, Ibibio, àti èèyàn Nupe láàárin àwọn ọ̀wọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yòókù. Àwọn ọ̀wọ́ mìíràn wa látìta tí wọn wá láti àwọn ìlú tí ó pín ààlà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pèlú Saro (Sierra Leonean) àti Amaro (Brazilian) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀wọ́ tí wọn ṣẹ̀ wá tí wọ́n kó lẹru tẹ́lẹ̀rị́ tí wọ́n padà sílẹ̀ adúláwọ̀ ní àwọn ọdún 1800 pẹ̀lú àwọn àwùjọ àárín ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ti wà ti pẹ́ (pàápàá Syrian àti Lebanese orílẹ̀-èdè Nàìjíríà)[9] pẹ̀lú di èrò ní apákan gbòógì ní ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ṣí wá láìpẹ́ láti ìlu Benin, China, Ghana, India, Togo, àti United Kingdom.[10][11][12][13]
Babájídé Sanwóolú ni gómìnà ìpínlè Èkó.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.