Ìpínlẹ̀ Borno
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Remove ads
Ìpínlẹ̀ Borno jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní agbègbè àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Yobe sí ìlà-oòrùn, Ìpínlẹ̀ Gombe sí gúúsù-ìlà-oòrùn, àti Ìpínlẹ̀ Adamawa sí gúúsù nígbà tí ó àwọn ààlà ìlà-oòrùn rẹ̀ parapọ̀ di ààlà orílẹ̀ èdè pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Cameroon, ààlà àríwá rẹ̀ parapọ̀ di ààlà orílẹ̀ èdè pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Niger, àti ààlà àríwá-ìlà-oòrùn rẹ̀ parapọ̀ di ààlà orílẹ̀ èdè pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Chad, léyìí tí ó mu jẹ́ ìpínlẹ̀ Nàìjíríà kan tí ó pín ààlà pẹ̀lú pín ààlà pẹ̀lú méta. Ó mú orúkọ rẹ̀ látara ìlú onítan emirate ti Borno, pẹ̀lú emirate àtijọ́ ti olú-ìlú Maiduguri tí ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olú-ìlú ìpínlẹ̀ Borno. Wọ́n dáa sílẹ̀ ní ọdún 1976 nígbàtí Ìpínlẹ̀ àríwá-ìlà-oòrùn tẹlẹri fọ́. Ó pẹ̀lú agbègbè tí a mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Yobe báyìí, tí ó di ìpínlẹ̀ tí ó dá yàtọ̀ ní ọdún 1991.[3]
Remove ads
Ìpínlẹ̀ Borno jẹ́ gbègbè ẹlẹ́ẹ̀kejì tí ó gbòòrò jùlọ láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, òhun nìkan ló wà lẹ́yìn Ìpínlẹ̀Niger. Pẹ̀lú bí ààye rẹ̀ ṣe rí, ìpínlẹ̀ náà jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè pẹ̀lú ènìyàn tí ó tó mílíọ́nnù mẹ́fà-dín-ní-díẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àbájáde ọdún2016.[4]
Ìpínlẹ̀ Borno ní olùgbé láti bí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kúnfún àwọn oríṣiríṣi ẹ̀yà pẹ̀lú Dghwede, Glavda, Guduf, Laamang, Mafa, àti Mandara ní àáríngbùngbùn ẹkù náà; àwọn ará Afade, Yedina (Buduma), àti Kanembu ní gbùnnùgbúnnù àríwá-ìlà-oòrùn; àwọn ará Waja ní gbùnnùgbúnnù gúúsù; àti àwọn ará Kyibaku, Kamwe, Kilba, Margi groups àti babur ní gúúsù nígbàtí àwọn ará Kanuri àti Shuwa Arabs ń gbé ní jákèjádò àríwá àti àáríngbùngbùn ìpínlẹ̀ náà.
Remove ads
Itokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Remove ads