Ìpínlẹ̀ Òndó
Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà / From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Ondo jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù-ìwọ̀oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. wọ́n da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejí ọdún 1976 látara àwọn Ìpínlẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn tẹ́lẹ̀ rí.[4] Ìpínlẹ̀ Ondo pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ekiti sí àríwá, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Edo sí ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Delta sí gúúsù-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ogun sí gúúsù-ìwọ̀ oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Osun sí àríwá-ìwọ̀ oòrùn, àti pẹ̀lú Atlantic Ocean sí gúúsù.[5] Tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Akure, ìyẹn olú-ìlu ẹkùn-ìjọba Akure àtijọ.[6] Ìpínlẹ̀ Ondo ni igbó mangrove-swamp wà lẹ́ba àwọn ìgbèríko ìlu Benin.[7]
Ondo State State nickname: Sunshine State | ||
Location | ||
---|---|---|
Statistics | ||
Governor (List) |
Oluwarotimi Odunayo Akeredolu (-) | |
Date Created | 3 February 1976 | |
Largest City | Ondo | |
Capital | Akure | |
Area | 14,606 km² Ranked 25th | |
Population 1991 Census 2005 estimate |
Ranked 20th 3,884,485 4,011,407 | |
ISO 3166-2 | NG-ON |
Ondo | |||
---|---|---|---|
| |||
Nickname(s): | |||
Location of Ondo State in Nigeria | |||
Coordinates: 7°10′N 5°05′E | |||
Country | Nigeria | ||
Date created | 3 February 1976 | ||
Capital | Akure | ||
Government | |||
• Body | Government of Ondo State | ||
• Governor (List) | Rotimi Akeredolu (APC) | ||
• Deputy Governor | Lucky Aiyedatiwa (APC) | ||
• Legislature | Ondo State House of Assembly | ||
• Senators | C: Akinyelure Patrick Ayo (APC) N: Robert Ajayi Boroffice (APC) S: Nicholas Tofowomo (PDP) | ||
• Representatives | List | ||
Area | |||
• Total | 15,500 km2 (6,000 sq mi) | ||
Population (2006 census)1 | |||
• Total | 3,460,877[1] | ||
• Rank | 18th of 36 | ||
GDP (PPP) | |||
• Year | 2007 | ||
• Total | $8.414 billion[2] | ||
• Per capita | $2,392[2] | ||
Time zone | UTC+01 (WAT) | ||
postal code | 340001 | ||
ISO 3166 code | NG-ON | ||
HDI (2018) | 0.606[3] medium · 16th of 37 | ||
^1 Preliminary results |
Tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ njẹ́ "Sunshine State", Ìpínlẹ̀ Ondo jé ọ̀kàndìnlógún Ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,[8] tí ó sì jẹ́ ìpínlẹ̀ karùndínlọ́gbọ̀n tó fẹ̀ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ilẹ̀ gbígbà.[9] Yorubani ó gbilẹ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà,[10][11] èdè Yorùbá ni wọn ń sọ jù níbẹ̀.[12] Ilé-iṣẹ́ epo-bẹntiróò ni ó gbilẹ̀ jù gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé ní ìpínlẹ̀ náà. òwo Cocoa, wíwa asphalt, àti àwọn ọ̀gọ̀rọ̀ iṣẹ́ etí òkun pẹ̀lú èto ọrọ̀-ajé ìpínlẹ̀ náà.[13] Ilé àwọn òkè Idanre ni, tí ó kó ipa tó ga jùlọ nínú ìdajì àwọn agbègbè ìwọ̀-oòrùn tí ó làmìlaka lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó ga ju ìwọn ọgọ́run mítà lọ ní títayọ.