From Wikipedia, the free encyclopedia
Ọláwálé Gladstone Emmanuel Rótìmí tí a mọ̀ sí Olú Rótìmí (13 Oṣù kẹrin 1938 – 18 Oṣù kẹjọ 2000),[1] jẹ́ ògbóńta olùkọ̀tàn, ọmọ orìlé èdè Nàìjírìà àti olùdarí tíátà . Wọn a má pèé ní "Okùnrin oní tíátà tí kò lábàwọń –òṣèré, olùdarí , onijo kòríógíráfì, àti oníṣẹ́-ọnà – tí ó ṣe àyè iṣẹ́, tí ọnà kópa ní ìgbésí ayé rẹ̀".[2].Ola Rotimi ni ko iwe The Gods are not to blame
Ọlá Ròtìmí | |
---|---|
Ọjọ́ ìbí | Ọláwálé Gladstone Emmanuel Ròtìmí 13 Oṣù Kẹrin 1938 Sapele, Delta State, Nàìjíríà |
Ọjọ́ aláìsí | 18 August 2000 ọdún 62) | (ọmọ
Iṣẹ́ | Playwright, director. head of department of creative arts at the University of Port Harcourt, Lecturer at Obafemi Awolowo University, Nigeria; has also served as visiting professor, playwright, and director in Germany and Italy, as well as at DePauw University and Wabash College. |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ìgbà | 1938–2000 |
Notable works | The Gods Are Not To Blame, Ovonramwen Nogbaisi, and The Epilogue |
Rotimi jẹ́ ọmọ Samuel Gladstone Enitan Rotimi, ọmọ yorùbá ẹlẹ́rọ tí àwọn òyìnbó ń pè ní "steam-launch engineer" (ó jẹ́ olùdarí àti alagbéjáde àwọn òṣèré tí kò tí ì dí ògbóntà) àti Dorcas Adolae Oruene Addo, ọmọ Ijaw tí ó fẹ́ran eré ìtàgé. Wọ́n bíi sí ìlú Sapele ní Nàìjíría; Onírúúru àṣà ni àkòrí iṣẹ́ rẹ̀. Ó lọ sí ilé ìwé Cyprian ni ìlú Port Harcourt láti ọdún 1945 sí 1949, ilé ìwé St Jude láti ọdún 1951 sí 1952 àti ilé ìwé Methodist Boys High School ní ilú Èkó, kí ó tó rìriǹàjò lọ sí United States ni ọdún 1959 lati kọ́ ẹ̀kọ́ ni Boston University, níbi tí ó ti gba oyè àkọ́kọ́ ní áàtì (B A). Ní ọdún 1965, ó fẹ́ aràbìrin Hazel Mae Guadreau, tí ó kọ́kọ́ wá lati Gloucester; Hazel kàwé ní Boston University, níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kó ijó, ohún àti orin. Ní ọdún 1966, Olá gba oyè kejì (MA) lati ilé ìwé Yale School of Drama,níbi tí ó tí olùkọ́ eré kíkọ eré lítíréṣò.
Rotimi ma ń ṣàyẹ̀wò ìtàn Nàíjíríà àti àṣ̀à nínú irẹ́ rẹ̀. Wọn ṣe àfifàn eré rẹ̀ àkọ́kọ́, To Stir the God of Iron (gbejade ní 1963) àti Our Husband Has Gone Mad Again (gbejade ní 1966; tẹjade ní 1977) ní ilé ẹ̀kọ́ orí ìtàgé ti Boston University àti Yale University.
Nígbàtí ó padá sí Nàìjíríà ní bíi 1960, ṣisẹ́ olùkọ́ ni Yunifàsíti Ifẹ̀ ti wọ́n ń pè ní Ọbáfẹ́mi Awólòwọ̀ Yunifásit̀ì nísìn, níbi tí ó tí dà ilé iṣẹ́ Olokun Acting Company[3] àti Port Harcourt sílẹ̀. Lápákan, nítoní ètò òṣèlú Nàìjíríà, Rotimi lo púpọ̀ nínu 1990s ẹ́ ní Caribbean àti United States, níbi ti ó ti kọ́ akẹkọ ní ilé ìwé Macalester College ní St. Paul, ní Minnesota. Ni odún 2000, ó padà sí Ilè Ifẹ̀, ó darapọ̀ ẹ̀ka èkọ́ Ọbáfẹ́mi Awólòwọ̀ Yunifásit̀ì níbí tí ó tí ṣisẹ́ olùkọ́ tí ó fi kú. Hazel (ìyàwó rẹ́) kú ní Oṣù karun odún 2000, oṣù díẹ sí ìgbà tí Rotimi kú.
Àwọn eré tí ó ṣe ní The Gods Are Not to Blame (gbejade 1968; tẹ̀jade 1971), àtúnsọ Sophocles Oedipus the King, Kurunmi and the Prodigal (gbejade 1969; tẹ̀jade bíi Kurunmi, 1971), tí ó kọ fún Ife Festival of Arts; Ovonramwen Nogbaisi (gbejade 1971;tẹ̀jade 1974), nípa Oba Benin empire; àti Holding Talks (1979).
Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n ṣe àfihàn àwọn eré :A Tragedy of the Ruled (1983) àti Hopes of the Living Dead (1988), tó ṣe ní University of Port Harcourt, ó jẹ́ eré tó gbòpò ní ẹ̀ka tíátà OAU. Radio play Everyone His/Her Own Problem diàtẹjade ní odún 1987. Ìwé rẹ̀, African Dramatic Literature: To Be or to Become? di titejade ní odún 1991
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.