Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìpínlẹ̀ Bayelsa jẹ́ ìpínlẹ̀ kan láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní agbègbè Gúúsù-Gúúsù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. tí ó wà ní gbùnnùgbúnnù agbègbè Niger Delta.[1][2] Wọ́n dá Ìpínlẹ̀ Bayelsa[3] sílẹ̀ ní ọdún 1996 wọ́n sì dá ààyè rẹ̀ yọ kúrò nínú Ìpínlẹ̀ Rivers,[4] ní èyí tí ó mu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ titun ní orílẹ̀ èdè. Yenagoa ni olú-ìlú rẹ̀. Ìpínlẹ̀ Bayelsa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè rẹ̀ bọ́sí ibi ẹ̀kun-omi tí ó léwu jùlọ, tí ó ṣeéṣe kí ó máa sẹlẹ̀ lọ́dọọdún. Ó pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Rivers[4] sí ìlà-oòrùn àti Ìpínlẹ̀ Delta sí ìlà-oòrùn, pelu àwọn omi ti Atlantic Ocean[5] ti ó jẹ gàba lórí àwọn ààlà gúúsù rẹ̀.[2] Ó ní agbègbè tó tó 10, 773 km2.[6] Ìpínlẹ̀ náà ṣàkónú agbègbè ìjọba ìbílè mẹ́jọ. Àwọn sì Ekeremor, Kolokuma/Opokuma, Yenagoa, Nembe, Ogbia, Sagbama, Brass àti Gúúsù-Ijaw.[2] Ìpínlẹ̀ náà pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Rivers,[7] ní èyí tí oh jẹ́ apákan tẹ́lẹ̀rí, àti Ìpínlẹ̀ Delta.[8][9][10]
Ipinle Bayelsa State nickname: Glory of all lands | ||
Location | ||
---|---|---|
Statistics | ||
Governor (List) |
Seriake Henry Dickson (PDP) | |
Date Created | 1 October 1996 | |
Capital | Yenagoa | |
Area | 10,773 km² Ranked 27th | |
Population 1991 Census 2005 est. |
Ranked 35th N/A 1,998,349 | |
ISO 3166-2 | NG-BY |
Èdè Ijaw,[11] ni ó gbòòrò jù ní sísọ Ìpínlẹ̀ Bayelsa pẹ̀lú Isoko àti Urhobo tí wọ́n sọ ní àwon ìlú àbáláyé ní Ìpínlẹ̀ náà. Ó jẹ́ ìlú àbáláyé fún àwọn ará Urhobo tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba ìbílè Sagbama.[12] Ó jẹ́ Ìpínlẹ̀ tí ó kéré jùlọ ní orílè-èdè Nàìjíríà[13] Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ètò-ìkànìyàn ọdún 2006, bákan náà ni ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè tí ó kéré jù ni ààyè.[2] Wíwà rẹ̀ ní agbègbe Niger Delta, Ìpínlẹ̀ Bayelsa ní odò àti ọ̀gbun níbi tí òkun tí pàdé, pẹ̀lú oríṣiríṣi omi láàárin Ìpínlẹ̀ náà ní èyí tí kò jẹ́ kí ìdàgbàsókè òpópónà tó ṣe gbòógì ó wáyé.[14]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.