Índíà
Orílẹ̀-èdè kan ní Guusu Asia / From Wikipedia, the free encyclopedia
Índíà, tàbí Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Índíà (ní èdè Híńdì: भारत गणराज्य Bhārat Gaṇarājya;), jẹ́ orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Éṣíà. Ohun ni orílẹ̀-èdè kejè títóbi júlọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtóbí jẹ́ọ́gráfì, orílẹ̀-èdè kìn-ín-ni tó ní ìye àwọn ènìyàn júlọ[11] pẹ̀lú bíi 1.43 bílíọ̀nù ènìyàn,[12] àti ìjọba-oníbò tó ni ìye àwọn ènìyàn júlọ̀ lágbàyé. Ó ja mọ Òkun Índíà ní gúúsù, Òkun Lárúbáwá ni ìwọ̀ oòrùn, àti Ebado Benga ní ìlà oòrùn, India ní etíkun tó jẹ́ 7,516.6 kilometres (4,700 mi)[13]. Ó ni ààlà láàrin Pakistan ní ìwọ̀ oòrùn; Ṣáínà, Nepal, ati Bhutan si àríwà; ati Bangladẹ́shì ati Burma ní ìlà oòrùn. Índíà wà nítosí Sri Lanka, àti Maldives tí wọ́n wà ní Òkun Índíà.
Olómìnira ilẹ̀ Índíà Republic of India भारत गणराज्य* Bhārat Gaṇarājya | |
---|---|
Olùìlú | New Delhi |
Ìlú tótóbijùlọ | Mumbai |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | Híńdì, Gẹ̀ẹ́sì |
Constitutional languages | |
Orúkọ aráàlú | Índíà |
Ìjọba | Olómìnira ìjọba àpapọ̀[4] |
• Ààrẹ | Droupadi Murmu |
• Vice President | Venkaiah Naidu |
• Prime Minister | Narendra Modi |
• Chief Justice | Sharad Arvind Bobde |
Aṣòfin | Sansad |
• Ilé Aṣòfin Àgbà | Rajya Sabha |
• Ilé Aṣòfin Kéreré | Lok Sabha |
Independence from United Kingdom | |
• Declared | 15 Oṣù Ògún 1947 |
• Republic | 26 Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ 1950 |
Ìtóbi | |
• Total | 3,287,240 km2 (1,269,210 sq mi)‡ (7th) |
• Omi (%) | 9.56 |
Alábùgbé | |
• 2009 estimate | 1,198,003,000[5] (2nd) |
• 2001 census | 1,028,610,328[6] |
• Ìdìmọ́ra | 364.4/km2 (943.8/sq mi) (32nd) |
GDP (PPP) | 2008 estimate |
• Total | $3.298 trillion[7] (4th) |
• Per capita | $2,780[7] (130th) |
GDP (nominal) | 2008 estimate |
• Total | $1.206 trillion[7] (12th) |
• Per capita | $1,017[7] (143rd) |
Gini (2004) | 36.8[8] Error: Invalid Gini value |
HDI (2007) | 0.612[9] Error: Invalid HDI value · 134th |
Owóníná | Indian rupee (₨) (INR) |
Ibi àkókò | UTC+5:30 (IST) |
• Ìgbà oru (DST) | UTC+5:30 (not observed) |
Ojúọ̀nà ọkọ́ | left |
Àmì tẹlifóònù | 91 |
ISO 3166 code | IN |
Internet TLD | .in |
Non-numbered Footnotes:
* Bharat Ganarajya, that is, the Republic of India in Hindi,[4] written in the Devanāgarī script. See also other official names
‡ This is the figure as per the United Nations though the Indian government lists the total area as 3,287,260 square kilometres.[10] |
Gẹ́gẹ́ bíi ilẹ̀ Ọ̀làjú Àfonífojì Indus jẹ́ ibí tó ní ìdàgbàsókè púpọ̀, abẹ́orílẹ̀ Índíà jẹ́ ibi àwọn ènìyàn mọ̀ fún ọlá àti àṣà rẹ̀ káàkiri ayé.[12] Esin nla merin, Hinduism, Buddhism, Jainism ati Sikhism ni won bere latibe, nigbati Zoroastrianism, Esin Ju, Esin Kristi ati Imale de sibe ni egberundun akoko IO (CE) won si kopa ninu bi orisirisi asa agbegbe na seri. Diedie o je fifamora latowo British East India Company lati ibere orundun ikejidinlogun, o si di ile amusin Ile-oba Isodokan lati arin orundun ikandinlogun, India di orile-ede alominira ni 1947 leyin akitiyan fun isominira to se pataki fun isatako alaise jagidijagan kakiri.[14]
India je orile-ede olominira kan to ni ipinle 28 ati awon agbegbe isokan meje pelu sistemu onileasofin oseluaralu. Okowo India ni okowo ikokanla titobijulo gege bi olorujo GDP lagbaye ati ikerin titobijulo gege bi ibamu agbara iraja. Otun je omo egbe Ajoni awon Orile-ede, G-20, BRIC, SAFTA ati Agbajo Owo Agbaye. India je orile-ede toni ohun-ijagun bombu inuatomu, o si ni ile-ise ologun ikewa ton nawojulo pelu ile-ise ologun adigun keji titobijulo lagbaye. Atunse okowo to bere lati 1991 ti so India di ikan ninu awon okowo to n dagba kiakia julo lagbaye;[15] sibesibe, aini si tun ba ja,[16] aimookomooka, iwa-ibaje, arun, ati aijeunkanu. Gege bi awujo esin olopolopo, eledepupo ati eleya eniyan pupo, India tun je ibugbe fun opolopo awon eran-igbe ni opolopo ibi alaabo.