Ẹ̀sìn Islam
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ẹ̀sìn Ìmàle tabi Ẹ̀sìn Islàm (Lárúbáwá: الإسلام al-’islām, pronounced [ʔislæːm] ( listen)[note 1])[1] jẹ́ ẹ̀sìn àlááfíà,ìrọ̀rùn àti ìjupá-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run aṣẹ̀dá gbogbo ayé nípa ṣ́iṣe ìfẹ́ àti títèlé àṣẹ rẹ̀ yálà o tẹ́ ọ lọ́rùn tàbí kò tẹ́ ọ lọ́rùn. Ó tún jẹ́ ẹ̀sin tí Ọlọ́run tún fi ránṣẹ́ sí gbogbo ayé látọwọ́ àwọn òjíṣ̣́e rẹ̀ tó ti rán wá ṣáájú ànọ́bì Muhammad ọmọ Abdullah (kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun ó ma bá a). Òun sì ni ẹ̀sìn òtítọ tí ẹ̀sìn mìíràn kò lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gb̀a ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun (Allah) yàtò sí òun nìkan. Ọlọ́hun (Allah) sì ti ṣe é ní ẹ̀sìn ìrọ̀rùn tí kò sí ìṣòro kankan tàbí wàhálà níbẹ̀. Kò si ohun tí ó kọjá agbára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìjẹni nípá fún àwọn tí wọ́n gba èsìn náà. Bẹ́è sì tún ni ẹ̀sìn náà kò la ohun tí ó kọjá agbára wọn bọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ìsìlámù ni ẹ̀sìn tí ó ṣe pé ìmọ̀-Ọlọ́hun ni (al- Taoheed) ní ìpìl̀ẹ rè, òdodo ni òpó rẹ̀, ó dá lórí déédé,otito. Òhun sì ni ẹ̀sìn tí ó gbópọn tí ó jẹ́ pé ó ń darí gbogbo ẹ̀dá sí ibi gbogbo ohun tí yó̀o jẹ́ ànfààní fún wọn ní ọ̀run àti ayé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì tún ń kì wọ́n nílọ̀ nípa gbogbo ohun tí yó̀o ṣaburú fún wọn yálà láyé ni tàbí ọ̀run. Òhun ni ẹ̀sìn tí Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe àtúnṣe àwọn àdì-ọ́kàn àti àwọn ìwà àìdáa kan. Òhun náà ni Ó fi ṣe àtúnṣe ìsẹ̀mí ayé àti ti ọ̀run. Òun ni Ọlọ́hun (Allah) fi ṣe ìrẹ́pọ̀ láàrin àwọn ọkàn tí ó kẹ̀yìn sí ara wọn àti àwọn ojúkòkòrò tí ó fọ́nká. Nípasẹ̀ èyí ni Ó fi yọ àwọn ohun tí a kà sí iwájú yìí nínú òkùnkùn biribiri ìró, tí Ó sì ṣe ìfinimọ̀nà rẹ̀ lọ sí ibi òtítọ́, tí Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà lọ sí ibi ọ̀nà tí ó yè kooro[2].
- Ẹ̀sìn Islam jẹ́ orúkọ iṣẹ́ ayélujára gbajúgbajà tí Sheikh Dr. Abdul-Fattah Adelabu ẹni tí í ṣe olórí àti olùdásílẹ̀, Awqaf Africa àti Asíwájú Ẹ̀sìn fún àwọn aláwọ̀ dúdú ní ilẹ̀ Geesi dá sílẹ̀ láti ipaṣẹ̀ EsinIslam.com fún ẹ̀kọ́ nípa Ẹ̀sìn Islam pẹ̀lú Awqaf Africa Muslim Open College ní ìlú London.