![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/67/Ataoja_of_Oshogbo-min.jpg/640px-Ataoja_of_Oshogbo-min.jpg&w=640&q=50)
Òṣogbo
Olú Ìlú ìpínlè Osun àti ìjoba agbègbè ìbílè ní orílè-èdè Nàìjíríà / From Wikipedia, the free encyclopedia
Òṣogbo jẹ́ ìlú ńlá kan ní ìpílẹ̀ Ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bákan náà ni ó jẹ́ olú ìlú fún ìpínlẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ọ̀gbẹ́ni Gbóyèga Òyètọ́lá ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lọ́wọ́lọ́wọ́. Òṣogbo di olú ìlú fụ́n Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọdun 1991.[1] Bákan náà ni ó tún jẹ́ olú ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ fún ìlú Òṣogbo, tí ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà sì wà ní Òke Báálẹ̀, nígbà tí ìjọba ìbílẹ̀ Ọlọ́rundá ń ṣojú agbègbè Ìgbóǹnà nílú Òṣogbo.[1][2]
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/6/67/Ataoja_of_Oshogbo-min.jpg/640px-Ataoja_of_Oshogbo-min.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/b/bf/Osogbo.jpg/640px-Osogbo.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/7/7e/Locator_Map_Oshogbo-Nigeria.png/200px-Locator_Map_Oshogbo-Nigeria.png)