![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/a/ab/%25C3%2592gb%25C3%25B3j%25C3%25BA_%25E1%25BB%258Cd%25E1%25BA%25B9_N%25C3%25ADn%25C3%25BA_Igb%25C3%25B3_Ir%25C3%25BAnm%25E1%25BB%258Dl%25E1%25BA%25B9%25CC%2580.jpg/640px-%25C3%2592gb%25C3%25B3j%25C3%25BA_%25E1%25BB%258Cd%25E1%25BA%25B9_N%25C3%25ADn%25C3%25BA_Igb%25C3%25B3_Ir%25C3%25BAnm%25E1%25BB%258Dl%25E1%25BA%25B9%25CC%2580.jpg&w=640&q=50)
Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ tí ọ̀mọ̀wé D.O. Fagunwa kọ ní ọdún 1938. Ó jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ tí a kọ́kọ́ kọ ní èdè Yorùbá,[1] [2] tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ìwé ìtàn tí a má a kọ́kọ́ kọ ní èdè Àfíríkà [3] . Ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò ògbójú Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àkàràògùn, àti ohun tí ojú rẹ̀ rí lóríṣiríṣi nínú ìrìn-àjò rẹ̀ nínú igbó. Àwọn nkan bí idán, iwin, ẹbọra àti àwọn òòṣà orísirísi ṣe fìtínà rẹ̀ nínú igbó tí òǹkọ̀wé pè ní igbó irúnmọlẹ̀. Ó jẹ́ ìwé ìtàn-àròsọ méèrirí tí a ka ní èdè Yorùbá. Ìwé ìtàn àròsọ tí ó tẹ̀lé ìwé yí láti ọwọ́ ònkọ̀wé kan náà ni Ìgbó Olódùmarè. Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyinká ṣe ògbufọ̀ ìwé ìtàn àròsọ Ògbójú Ọdẹ nínú Igbo Olódùmarè sí èdè Gẹ̀ẹ́sì.[4] bíi Igbo Olodumare, it was adapted for the stage, in both English and Yoruba.[5]
![]() First edition (UK) | |
Olùkọ̀wé | Daniel O. Fagunwa |
---|---|
Illustrator | Mr. Ọnasanya |
Cover artist | Ọnasanya |
Country | Nigeria |
Language | Yorùbá |
Genre | fantasy |
Publisher | Nelson Publishers Limited in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Limited |
Publication date | written in 1938, published in 1950 |
Pages | 102 |
ISBN | Àdàkọ:ISBNT |
Preceded by | First book |
Followed by | Igbó Olódùmearè |