Remove ads
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìtàn ilẹ̀ Nàìjíríà ni a lè tọpa rẹ̀ sí nkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ó lé ọgórùún ọdún sẹ́yìn káàkiri àwọn abúlé, ìletò àti àwọn ìlú káàkiri Àrin gbùngbùn ìlà-Oòrùn àti gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà pátá (1100 BC). Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ìlú jànkàn jànkàn ìgbà láé láé tí wọ́n ti lajú tínwọ́n sì ti ń ṣèjọba ara wọn ṣáájú ọ̀làjú ayé òde òní ni wọ́n ti wà tí wọ́n sì para pọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Lára àwọn ìlú bẹ́ẹ̀ ni a ti rí Ilẹ̀ Ọba Bìní, Ilẹ̀ Ọba ti Ọ̀yọ́ àti Ilẹ̀ Ọba ti Ńri ti àwọn ẹ̀yà Ìgbò. Ẹ̀sìn Ìmàle wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti apá Àríwá pàá pàá jùlọ ilẹ̀ Ọba Bọ̀nú láàrín ọdún (1068 Ad) [1][2][3][4] Nígbà tí ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ wọ àárín àwọn ènìyàn ilẹ̀ Nàìjíríà láti ọwọ́ ọ̀gbẹ́ni Augustinian àti Capunchin tí wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùtàn láti orílẹ̀-èdè Potogí ní ọ̀rùndún kẹèédógún 15th century. ilé Ọba Songhai mú díẹ̀ lára ilẹ̀ Nàìjíríà.[5]
Ipa tí òwò-ẹrù nínú ìtàn orílẹ̀-èdè !Nàìjíríà kò kéré rárá,[6] òwò-ẹrù tí ó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀rùndún kẹẹ̀ẹ́dógún tí àwọn ará Potogí mú ẹ̀sìn [[ìgbagbọ́ wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn olówò-ẹrú yí tí wọ́n jẹ́ ará ilẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n ń pàgọ́ sí etí òkun. Ibi tí wọ́n àwọn olówò-ẹrú Potogí àti Brítènì]] kọ́kọ́ fojú sùn tí wọ́n sì kọ́ ilé òwò-ẹrù wọn sí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ìlú Àgbádárìgì, tí ó jẹ́ ìlú tí wà létí alagba-lúgbú omi[7] Ní ìlú yí, àwọn ojúkò tí wọ́n ma ń lò láti fi so àwọn tí wọ́n bá kó lẹ́rú sí ni ó ṣì wà níbẹ̀ títí di ọ̀là. Lẹ́yìn èyí ni.wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn alàgata láti báwọn wá àwọn ènìyàn tí wọn yóò fi ṣẹrú ní ìlú wọn. Ìgbésẹ̀ àwọn òyìnbó olówò-ẹrú yí mú ìtàpórógan tí ó dá ìjà gidi kalẹ̀ láàrín àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ Nàìjíríà lóriṣiríṣi tí ó sì ba òwò ati kárà-kátà gbogbo tí ó ń wáyé ní etí òkun jẹ́. [8]
Àwọn ọmọ ogun Gẹ̀ẹ́sì ará ilẹ̀ Brítènì kọlu ìlú Èkó ọdún 1851 tí wọ́n sì sọ ú Èkó di ìlú amónà ilẹ̀ Brítènì ní ọdún 1865.[9] orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ìlú tí ó gbọ́dò tẹ̀lé àṣẹ pẹ́lú ìlànà ìlú alágbára tí ó ń dáàbò bòó lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ìlú alágbára mìíran ní ọdún 1901, nígbà tí wọ́n jẹ gàba lé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí títí di ọdún 1960, nígbà tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà ja ìjà-n-gbara kúrò lọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn.[10]
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà di orílẹ̀-èdè tí ó ń ṣèjọba ara rẹ̀ ní ọdún 1963, àmọ́ ìjọba rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ológun tí wọ́n sì lo ọdún mẹ́ta gbáko. Lẹ́yìn ìdìtẹ̀ gbajọba ọdún 1966, àwọn ẹ̀yà Ìgbò kéde wípé àwọn ya kúrò lára ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àwọn sì ti dá ìjọba ẹkùn tiwọn sílẹ̀ tí wọ́n pè ní Bifra ní ọdún 1967, rògbòdìyàn yí náà tún dá ogun abẹ́lé sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún odidi ọdún mẹ́ta mìíràn. [11] Ìjọba àwa-arawa ẹlẹ́kejì tún bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àpérò àti àtúnṣe sí òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà í ọdún 1979. Bí ó tilẹ̀ jè pé, ìjọba náà kò pẹ́ lọ títí kí àwọn ológun tún tó dìtẹ̀ gba ìj9ba náà ní ọdún 1983 sí ọdún 1987 tí ó jẹ́ ọdún mẹrin gbáko. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún gbèrò láti gbé ìjọba àwa-arawa mìíràn kalẹ̀ ní ọdún 1993, àmọ́ Ààrẹ ológun apàṣẹ wàá Sani Abacha kọ̀ láti gbé ìjọba kalẹ̀ títí Nigeria became a republic once again after a new constitution was written in 1979. However, the republic was short-lived, when the military seized power again for another four years. A new republic was planned to be established in 1993, but was aborted by General Sani Abacha. Abacha died in 1998 and a fourth republic was later established the following year, which ended three decades of intermittent military rule.[12][13]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.