Èkó (tàbí Lagos ní èdè Gẹ̀ẹ́sì /ˈleɪɡɒs/, US also /ˈlɑːɡoʊs/;[1] Yorùbá: Èkó) ni ìlú tó ní èrò tó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní gbogbo ilẹ̀ Áfríkà.[2][3] Èkó jẹ́ ilé-ajé pàtàkì ní gbogbo Áfríkà àti oríta okòwò ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Èkó gẹ́gẹ́bí ìlú-nínlá ni ó ní GDP kẹrin tó pọ̀ jùlọ ní Áfríkà,[4][5] ibẹ̀ sì ni èbúté ọkọ̀-ojúomi tó tóbi jùlọ àti tó láápọn jùlọ ní ilẹ̀ Áfríkà.[6][7][8] Èkó ni ìkan láàrin àwọn ìlú tí ó ń ní ìgbèdàgbà kíákíá jùlọ ní àgbáyé.[16]
Lagos Èkó | |||
---|---|---|---|
| |||
Map of Lagos Metropolis | |||
Country | Nigeria | ||
State | Lagos State | ||
LGA | Lagos Island | ||
Area | |||
• Urban | 999.6 km2 (385.9 sq mi) | ||
Population (2006 census, preliminary) | |||
• Density | 7,941/km2 (20,569.9/sq mi) | ||
• Urban | 7,937,932 | ||
Time zone | UTC+1 (CET) | ||
Website | http://www.lagosstate.gov.ng/ |
Èkó ní orúkọ tí àwọn Yorùbá ń pè ìlú erékùsù tí ó ti di olú ìlú àti ibùjókòó ìjoba gbogbo-gbòò fún ilè Nàìjíríà ní ojó òní. Ìlú Yorùbá ni, ṣùgbọ́n orúkọ tí àwọn ènìyàn àgbáyé fi ń pè é ni èyí ti àwọn Òyìnbó Potogi tí ó kọ́ bẹ etíkun ilẹ̀ Yorùbá wò fún un. Orúkọ náà ni “Lagos”, èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ jásí “adágún” tàbí “ọ̀sà”, nítorí pé ọ̀sà ni ó yí ìlú náà ká...
Àwọn Ẹ̀yà Yorùbá ti Àwórì ni ó kọ́kọ́ tẹ̀dó si agbègbè Ìlú Èkó, lábé ìṣàkóso àti Ìtọ̀nà olórí wọn, Ọlọ́fin, àwọn Àwórì kọ́kọ́ tẹ̀dó sí erékùsù Ìddó, Lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ní wọnú àwọn agbègbè yókù Èkó láti tẹ̀dó. Ní séńtúrì karùndínlógún {15th Century}, Ìlú Èkó, bọ́ sí abẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Benin. Ìgbà náà ni àwọn Ológun Ìlú náà sọ agbègbè ìlú náà ní Èkó, eléyìí, tí ó túmò sí [Ibi tí àwọn Ológun tí ń simi} Ní èdè Edo/Benin. Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ lábẹ́ olórí àwọn Benin ní ìgbà náà Ọba Ọ̀rọ̀gbà. Léyìn tí èyí ṣẹlẹ̀, ni Ìjọba Benin fi Baálẹ̀ jẹ́ oyè, láti máà M'ójútó/Ṣe Àkóso, àti Gbígba Ìṣákọ́lè {Tribute} ìlú náà bíi agbègbè lábé-fé Ìjọba ńlá ti Benin. Ọba Yorùbá àkọ́kọ́ tí ó jẹ ní Ìlú Èkó ni Ọba Aṣípa. Ní ọdun-ún 1472, àwọn Òyìnbó Pọ́tókì{Portuguese} dé sí ilẹ̀ Èkó, àwọn Pọ́tókì náà ní Òyìnbó àkọ́kọ́ , tí ó máa dé Ilẹ̀-Èkó Erékùsù láti Orílè-ẹ̀dẹ̀ Europe ní ìgbà náà.