Sharon Ooja
òṣèré orí ìtàgè ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjírírà From Wikipedia, the free encyclopedia
Sharon Ooja tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹrin ọdún 1991 jẹ́ òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò ọmọ Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́yìn tó kópa nínú eré kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Skinny Girl in Transit, nínú èyí tí ó kópa ẹ̀dá-ìtàn ṣaléwá .[2]
Ìgbésí-ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀
Sharon jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Benue, ṣùgbọ́n tí wọ́n bí sí Ìpínlẹ̀ Kaduna, tí wọ́n sìn tọ́ dàgbà ní Ìpínlẹ̀ Plateau lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣeré nígbà tí ó dèrò Eko lọ́dún 2013.[3] Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú iṣẹ́ ìròyìn ní Yunifásítì Houdegbe North American University Benin. Ọ̀un àti Timini Egbuson ti fìgbà kan ṣe olóòtú fún ètò ọ̀sẹ̀ oge tí ilé ìfowópamọ́, GTBank ṣe agbátẹrù rẹ̀ lọ́dun in 2017.[4]
Àtòjọ àṣàyàn àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
- Coming from Insanity (2020)
- Òlòtūré (2019)
- King of Boys (2018)
- Skinny Girl in Transit (2016-)
- Lara and the Beat[5]
- Coming From Insanity
- Moms at War[6]
- From Lagos with Love (2018)
- The Men's Club
- Bling Lagosians (2019)
- Who's The Boss
Àwọn ìtọ́kasí
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.