Olu Jacobs
From Wikipedia, the free encyclopedia
Olúdọ̀tun Jacobs|Olú Jacobs (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlá oṣù keje ọdún 1942), jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́kà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ Yorùbá láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù.[2]
Olu Jacobs | |
---|---|
![]() | |
Ọjọ́ìbí | 11 Oṣù Keje 1942[1] Abeokuta, Ogun State, Nigeria |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 1970-present |
Olólùfẹ́ | Joke Silva |
Lọ́dún 2007, ó gba àmì ẹ̀yẹ African Movie Academy Award gẹ́gẹ́ bí Òṣèrékùnrin tó dára jùlọ nínú ipò olú-ẹ̀dá-ìtàn .[3]
Jacob tí ni ipa nínú iṣẹ́ fíìmù ṣíṣe ní Nàìjíríà. Pẹ̀lú ìrírí rẹ̀ tó ju ogójì ọdún lọ, a lè pè é ní alàgàta láàárín àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ àti àgbà òṣèré. Ní ọdún 2007, ó gba ààmì ẹ̀yẹ ti African Movie Academy Award fún òṣèré tó dára jù lọ.[4][5][6][7]
Àwọn Itokasi
Wikiwand - on
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.