Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia
Bọ́lá Ahmed Tinúbú (ọjọ́ ìbí Ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta, ọdun 1952) jẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ṣe ìbúra fún lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2023 lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ ọdun 2023.[1] Ó jẹ́ Gómìnà-àná Ìpínlẹ̀ Èkó láàrin ọdún 29 May odun 1999 títí di ọdún 29 May, 2007.[2] Àwọn ará ìlú ti kọ́kọ́ dìbò yàn Bola Ahmed Tinubu láti di Sẹ́nétọ̀ ní ọdún 1992, àmọ́ wọ́n fagilé ìbò náà ní ọdún (12 June, 1993)[3]
Bola Tinubu | |
---|---|
12th Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó | |
In office May 29, 1999 – May 29, 2007 | |
Asíwájú | Buba Marwa (military admin.) |
Arọ́pò | Babatunde Fashola |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 29 Oṣù Kẹta 1952 Lagos State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressive Congress |
Occupation | Politician |
Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kíní, ọdún 2022(January 11, 2022), Bola Ahmed kéde ète rẹ̀ láti dupò ààrẹ Nàìjíríà ní odún 2023 lábé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress(APC).[4] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 2022, Tinubu jáwé olúborí nínú ìdìbò-abẹ́lé ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress(APC) pẹ̀lú àmì ayò 1271, láti borí Igbákejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò àti Rotimi Amaechi tí ó gba 235(Osinbajo) àti 316(Rotimi).[5][6]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.