2face Idibia

Akọrin ti orílè-èdè Nàìjíríà, aṣàgbéjáde orin, àti onínúure From Wikipedia, the free encyclopedia

2face Idibia

Innocent Ujah Idibia (tí a bí sí ìlú Jos, ìpínlẹ̀ Plateau State, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ 2Baba, jẹ́ olórin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, akọrin sílẹ̀, agbọ́rin jáde àti onísẹ́ àdáni. Ní oṣù keje Odun 2014, ó yan 2face Idibia gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìtàgé rẹ̀.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin ilẹ̀ Áfíríkà tó ń kọ orin Afro pop tí ó lọ́lá jùlọ tí ó sì gbayì.[2] Ó ti lé lógún ọdún tí 2Baba tí ń kọrin tí ó sì ń dánilárayá ó sì jẹ́ ògbóǹtarìgì síbẹ̀.

Quick Facts 2Baba, Background information ...
2Baba
Thumb
2Baba attending the album release party for his sixth studio album, The Ascension.
Background information
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi2face Idibia
Ọjọ́ìbí18 Oṣù Kẹ̀sán 1975 (1975-09-18) (ọmọ ọdún 49)
Jos, Plateau, Nàìjíríà
Occupation(s)
  • Olórin
  • Olùkọ́ orin
  • Olùgbórin jáde
  • Oníṣòwò àdáni ní
Instruments
  • Vocals
  • vocal percussion
Years active1994–present
Labels
  • Hypertek Digital
Associated acts
Close

Ó tún jẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ.

Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀

A bí Innocent Idibia sí ìlú Jos, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Idoma ní apá gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó lọ sí Mount Saint Gabriel's Secondary School ní ìlú Makurdi, ìpínlẹ̀ Benue. Ó tún lọ sí Institute of Management & Technology (IMT) ní ìpínlẹ̀ Enugu níbi tí ó ti gboyè National Diploma nínú Business administration and management. Nígbà tí ó wà ní IMT, ó máa ń kọrin níbi ayẹyẹ àti àwọn ilé-ìwé gíga bíi University of Nigeria Enugu State University of Science & Technology. Kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kúrò nilé-ìwé ó sì gbájúmọ́ orin kíkọ. Ní ọdún 1996, ó yan "2face" gẹ́gẹ́ bíi orúkọ ìtàgé rẹ̀. [3]

Ní ọdún 2016, ó yí orúkọ ìtàgé rẹ̀ sí 2Baba.[4]

Orin rè

Àwọn àwo-orin

  • Face 2 Face (2004)
  • Grass 2 Grace (2006)
  • The Unstoppable (2009)
  • The Unstoppable International Edition (2010)
  • Away and Beyond (2012)[5]
  • The Ascension (2014)
  • Rewind, Select, Update (2015)
  • Warriors (2020)[6]

Àwọn Ìtọ́kasí

Loading related searches...

Wikiwand - on

Seamless Wikipedia browsing. On steroids.