Odun 2023 jẹ́ ọ̀kan nínú ọdún nínú kàlẹ́ndà Gìrẹ́górì. Ọdún 2023 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọjọ́ Àìkú nínú kàlẹ́ndà Gìrẹ́górì.
Oṣù kínní
- Ọjọ́ kẹjọ oṣù kínní(Jan 8)
- Àjàkáyé-àrùn Covid 19: Orílè-èdè China ṣí ààlà ilẹ̀ wọn fún àwọn àlejò láti orílè-èdè míràn, èyí jẹ́ òpin sí fífi òfin de àwọn ìrìn àjò kọ̀kan èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹta ọdún 2020.[4][5]
- Ìdìbọ̀ sí ilé ìgbìmò asofin ti orílè-èdè Benin wáyé.[6]
- Ọjọ́ kẹtàlá sí ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kínní(Jan 13 – Jan 14) – Ipele àkọ́kọ́ ti Ìdìbọ̀ ààrẹ orílè-èdè Czech wáyé.[7]
- Ọjọ́ keedogun oṣù kínní(Jan 15)– Ọkọ̀ bàlúù kan tí wón ń pè ní Yeti Airlines Flight 691 já ní Pokhara, orílè-èdè Nepal, ó sì pa ó kéré jù, ènìyàn kandinladorin.[8]
- Ọjọ́ kerindínlógún oṣù kínní(Jan 16) – Ọwọ́ ìjọba orílè-èdè Italy tẹ olórí ẹgbẹ jàndùkú kan tí wón ti ún wá fún ọjọ́ pípé, Matteo Messina Denaro ní Palermo, Sicily.[9]
- Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kínní (Jan 17) – Nguyễn Xuân Phúc kọ̀wé fisẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ààrẹ orílè-èdè Vietnam lẹyìn ọ̀pọ̀lopọ̀ ìwóde ìfẹ̀hónúhàn tako àwọn àìsedédé ìjọba rẹ̀.[10]
- Ọjọ́ ogún oṣù kínní(Jan 20)– Àwọn asọ̀fin orílè-èdè Trínídád àti Tòbágò yan Christine Kangaloo gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè náà.[11]
- Ọjọ́ keedogbon oṣù kínní(Jan 25)– Chris Hipkins rọ́pò Jacinda Ardern gẹ́gẹ́ bi Mínísítà àgbà orílè-èdè New Zealand,[12] ọjọ́ mefa lẹ́yìn tí Jacinda Ardern kọ̀wé fi ipò mínísítà àgbà sílè.[13]
- Ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n sí ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kínní (Jan 27–28) – Ipele kejì Ìdìbọ̀ ààrẹ orílè-èdè Czech ọdun 2023 wáyé, Petr Pavel ni ó jáwé olúborí.[14]
"সংবাদ বিজ্ঞপ্তি" (PDF). www.ecs.gov.bd (in Bengali). Bangladesh Election Commission. Archived from the original (PDF) on February 17, 2023. Retrieved 13 February 2023.