![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/a/a5/Glass_of_Milk_%252833657535532%2529.jpg/640px-Glass_of_Milk_%252833657535532%2529.jpg&w=640&q=50)
Wàrà
From Wikipedia, the free encyclopedia
Wàrà ni ohun mímu funfun olómi tí ó ní èròjà aṣara lóore tí a ma ńnfún láti ẹnu ọmú Màlúù, tí ó sì jẹ́ ìpìlẹ̀ èròjà ìdàgbà-sókè fún ọmọ màlúù tí ó bá ń mumú àti ọmọ ènìyàn pàá pàá, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun.[1] Nínú wàrà ni Kolósítírọ́ọ̀mù tí ó jẹ́ èròjà aṣara-lóore gan an sodo sí nígbà tí èyíkéyí ẹranko alégun lẹ́yìn afọ́mọ lọ́mú bá kọ́kọ́ fọ́mọ rẹ̀ lọ́mú. Kolósítírọ́ọ̀mù yí ni ó kún fún èròjà ọmọ ogun ara tí ó ń jáde láti ara ìyá sí ara ọmọ rẹ̀ tó ń mumú láti dáàbò bòó kúrò lọ́wọ́ àrùn àti àìsàn àìfojúrí, ó tún kún fún àwọn èròjà mìíràn tó ń ṣara-lóore.[2] Lára àwọn èròjà tí kolósítírọ́ọ̀mù kó sínú ni : èròjà amára-jọ̀lọ̀ (protein) àti èròjà afára-lókun (lactose). [3][4] [5][6]
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/a/a5/Glass_of_Milk_%2833657535532%29.jpg/640px-Glass_of_Milk_%2833657535532%29.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/3/3f/Melkkarussell.jpg/640px-Melkkarussell.jpg)