Sílíkọ́nù, tí èdè ìperí rẹ̀ ń jẹ́ tetravalentmetalloid, ni ó jẹ́ kẹ́míkà tí ó bí àmì Si tí atomic number rẹ̀ jẹ́ mẹ́rìnlá. Sílíkọ́nù kìí sábà á gbéra tó àwọn èròjà inú rẹ̀ bíi analog carbon. Wọ́n ṣàwárí sílíkọ́nù fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1823, wọ́n sì fun ní orúkọ rẹ̀ Sílíkọ́nù ní ọdún 1808 láti ara (flang Látìnì: silicis, flints), àti -ium , ọ̀rọ̀ tí gbẹ̀yìn yí ninú orúkọ rẹ̀ ni ó ń túmọ̀ wípé ẹ̀yà irin ni. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fun ní orúkọ Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ ní ọdún 1817.
Sílíkọ́nù yí ni ó ṣìkẹ́jọ nínú àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àlùmọ́nì jùlọ lágbàáyé, amọ́ kò wọ́pọ̀ láti rí. Àwọn ayè tí a ti lè ṣe alábala-pàdé rẹ̀ ni àwọn bíi: eruku, iyẹ̀pẹ̀ ,planetoid àti inú àwọn ìgbàjà ahòho sánmọ̀ (planets). Ó ma ń wà gẹ́gẹ́ bí silixon dioxide tàbí silicates, nígbà tí ó jẹ́ wípé ìdá àádọ́rùn orí ilẹ̀ àgbáyé ni ó ní èròjà silicates minerals tí ó sì mú kí sílíkọ́nù ó ya mùrá ní orí-ilẹ̀ ayé lẹ́yìn afẹ́fẹ́ oxygen.[8]