Polling Station
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ojúkò ìdìbò[1] jẹ́ ibi tí àjọ elétò ìdìbò pèsè kalẹ̀ fún àwọn olùdìbò tí wọ́n sì gbé àpótí ìdìbò sí kí ètò ìdìbò náà ó lè rọrùn. bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ojúkò ìdìbò sábà ma ń túmọ̀ sí odidi ilé tabí gbọ̀ngàn kan tí àwọn olùdìbò yóò kórajọ sí tí wọn yóò sì tó lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dìbò, amọ́, ojúkò ìdìbò gan gan ni ọ̀gangan ibi tí olùdìbò yóò ti dìbò fún olùdíje tí ó bá wùú.[2] Ojúkò yí sábà ma ń jẹ́ iyàrá kan tí àpótí ìbò wà tí olùdìbò kan ṣoṣo yóò wọ̀ lọ láti dìbò rẹ̀. [2] (or part of a room) where voters cast their votes. A polling place can contain one or more polling stations.[2] Nígbà tí ó jẹ́ wípé ètò ìdìbò gbogbo gbò sábà ma ń tó ọjọ́ kan sí ọjọ́ méjì tàbí kí ju bẹ́ẹ̀ lọ, ojúkò ìdìbò sábà ma ń jẹ́ ibùdó tí wọ́n ma ń ló fún nkan mìíràn gẹ́gẹ́ bí ilé ìjọsìn, pápá ìṣeré, ilé-ẹ̀kọ́, gbọ̀ngan ayẹyẹ, ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ilé ìgbé àwọn ènìyàn tí ó lè gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ibi tí ojúkò ìdìbò yí bá wà ni wọ́n ń pe ní wọ́ọ̀dù. Ojúkò ìdìbò yí ma ń jẹ́ ibi tí àwọn elétò ìdìbò àti elétò àbò tí wọn yóò ma tọ́ àwọn olùdìbò sọ́nà lórí ìgbésẹ̀ tí ó bá kàn tí àwọn elétò àbò yóò sì ma ṣàmójútó ìgbésẹ̀ ìdìbò kí ó lè já geere. Wọ́n ma ń ṣí Ojúkò ìdìbò yí sílẹ̀ fún àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ ìdìbò fún ìgbésẹ̀ ìdìbò, wọn sì kí ń gba ẹlòmíràn láàyè láti súnmọ́ apótí ìdìbò yàtọ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ dìbò àti àwọn olùdarí ètò ìdìbò pẹ̀lú àwọn elétò àbò tí wọ́n wà ní agbègbè náà.
Nínú ojúkò ìdìbò, ẹnu àpótí ìbò ni ni olùdìbò ti ma ń ní ànfaní láti lo ìwé ìdìbò láti fi yan olùdíje tí ó bá wú ní bòńkẹ́lẹ́ láì fi hàn fún ẹnikẹ́ni sínú àpótí ìbò. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n lè lo irinṣẹ́ kọ̀ọ̀kan láti fi ṣètò yí.
Ọpọ̀ ojúkò ìdìbò ni wọ́n ma ń jẹ́ fìdí hẹ, tí wọ́n sì ma ń ṣe atíbàbà síbẹ̀ fún ètò ìdìbò tí wọn yóò sì yọ àwọn ohun tí wọ́n ṣe síbẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò.