Nonso Diobi
From Wikipedia, the free encyclopedia
Nonso Diobi (tí wọ́n bí ní July 17, 1976) jẹ́ òṣèrékùnrin tó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. ó sì tún jé olùdarí fíìmù àgbéléwò[1][2][3][4] Lásìkò tó ń kékọ̀ọ́ nípa Theatre Art ní University of Nigeria, ó ṣe ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ọdún 2001, nínú fíìmù àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Border Line, léyìn náà ni ó tún kópa nínú fíìmú mìíràn tí àkọ́lé rè jẹ́ "Hatred". Ó sí tún tẹ̀síwájú láti fara hàn nínú fìímù kan tí àkólé rẹ̀ jẹ́ 'Across the bridge', èyí sì ló mu wá sí gbàgede, tó fi wá di gbajúgbajà káàkiri ilẹ̀ Africa[5].
Nonso Diobi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Nonso Diobi 17 Oṣù Keje 1985 (1985-07-17) (ọmọ ọdún 38) Enugu state, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2001 – present |
Website | linkedin.com/in/nonso-diobi-305aaa10a |
Diobi wá láti ìlú Nawfia, èyí tó jẹ́ ìlú kékeré kan ní Ipinle Anambra, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ àti alága ilé-iṣẹ́ Golden tape media. Ó jẹ́ aṣojú àlàáfíà fún UN àti aṣojú fún teachers without Borders[6]. Àwọn fíìmù tó ti kópa nínú ti ju mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76) lọ.[7][8]