![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/d/d1/Individual_plate_of_garri_to_eat_by_hand_with_fish_and_greens%252C_Baba1_%25285570984125%2529.jpg/640px-Individual_plate_of_garri_to_eat_by_hand_with_fish_and_greens%252C_Baba1_%25285570984125%2529.jpg&w=640&q=50)
Gàrí
From Wikipedia, the free encyclopedia
Gàrí ni ohun jíjẹ lẹ́bú-lẹ́bú kan tí ó ma ń ní awọ funfun tabí àwọ̀ órí tí wọ́n ma ń ṣe jáde láti ara ẹ̀gẹ́ tí a tún ń pè ní pákí. Irúfẹ́ ounjẹ yí wọ́pọ̀ ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀.[1] Oríṣiríṣi ohun tí wọ́n pèsè láti ara nkan bíi àgbàdo, ìrẹsì, iṣu tàbí ọkà bàbà tí wọ́n sì sọ di ìyẹ̀fun ni àwọn ẹ̀yà Hausa sábà ma ń pè ní gàrí, tí wọn yóò sì ma fi orúkọ ohun tí wọ́n fi ṣe ìyẹ̀fun náà kun. Àpẹẹrẹ ni: garin dawa, garin masara ati garin alkama' àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/d/d1/Individual_plate_of_garri_to_eat_by_hand_with_fish_and_greens%2C_Baba1_%285570984125%29.jpg/640px-Individual_plate_of_garri_to_eat_by_hand_with_fish_and_greens%2C_Baba1_%285570984125%29.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/8/8f/Manihot_esculenta_dsc07325.jpg/640px-Manihot_esculenta_dsc07325.jpg)
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/b/bd/PeeledCassava.jpg/320px-PeeledCassava.jpg)
Púpọ̀ nínú àwọn olùgbé àwọn orílẹ̀-èdè bíi: Nàìjíríà, Gánà, Togo, Benin Republic, Guinea, Cameroon àti Liberia ni wọ́n sábà ma ń jẹ gàrí gẹ́gẹ́ bí ounjẹ nígbà tí wọ́n bá fi gàrí tẹ ẹ̀bà nígbà tí wọ́n bá dà á sínú omi gbígbóná tabí kí wọ́n wà á mu nígbà tí wọ́n bá dà á sínú omi tútù.