Olóṣèlú From Wikipedia, the free encyclopedia
Àdàkọ:Use Nigerian English Àdàkọ:Refimprove
Admiral Augustus Aikhomu | |
---|---|
8th Vice President & Chief of General Staff | |
In office October 1986 – August 1993 | |
Ààrẹ | Ibrahim Babangida as Military President of Nigeria |
Asíwájú | Ebitu Ukiwe |
Arọ́pò | Oladipo Diya |
Chief of Naval Staff | |
In office January 1984 – October 1986 | |
Asíwájú | Akintunde Aduwo |
Arọ́pò | Patrick Koshoni |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 20 October 1939 |
Aláìsí | 17 August 2011 ọdún 71) | (ọmọ
(Àwọn) olólùfẹ́ | Rebecca Aikhomu |
Alma mater | Yaba College of Technology Britannia Royal Naval College NIPSS |
Military service | |
Allegiance | Nigeria |
Branch/service | Nigerian Navy |
Years of service | 1958–1993 |
Rank | Admiral |
Ọ̀gágun Augustus Akhabue Aikhomu tí wọ́n bí lógúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 1939,ti o sìn papòdà lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2011 jẹ́ Ọ̀gágun orí omi, olóyè Admiral tí orílẹ̀ èdè Nigeria, tí ó sìn jẹ́ Igbákejì Ààrẹ Ológun orílẹ̀-èdè Nigeria lábẹ́ Ààrẹ Ológun, Ọ̀gágun-yányán, General Ibrahim Babangida ní ọdún 1986 sí 1993.
Wọ́n bí Ọ̀gágun Augustus Aikhomu ní ìlú Idumebo-Irrua, ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó,[1] ní Nàìjíríà . Augustus lọ sí ilé-ìwé gíga ti Yaba College of Technology, Royal Britannia Naval College ní Dartmouth, England, Long Gunnery Specialist Course, India àti National Institute of Policy and Strategic Studies, Kuru, Nigeria.
Aikhomu dara pọ̀ mọ́ àwọn ológun orí omi Nigeria lọ́jọ́ kìíní oṣù Kejìlá ọdún 1958. Ó dára pọ̀ mọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ogún, Royal Navy gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́ ní HMSFisgard, lẹ́bàá Torpoint, East Cornwall ní oṣù kìíní ọdún 1959. Ó wà ní Grenville Division ní HMS Fisgard, tí ó sìn yẹ kí ó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ oṣù mẹ́rìndínlógún, abala kìíní rẹ̀ ní ìparí oṣù kẹrin ọdún 1960.
Aikhomu jẹ́ Ọ̀gágun-àgbà, NNS Dorina, Ọ̀gágun orí omi ní olú-ilé-iṣẹ́ àwọn ológun orí omi ní ọdún 1983 sí 1984. Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ chief of naval staff lọ́dún (1984–86).
Ọ̀gágun jẹ Nigeria, tí ó sìn jẹ́ Igbákejì Ààrẹ-ológun Nigeria lábẹ́ Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ní ọdún 1986 sí 1993.
Òun ni Alága àwọn ìgbìmọ̀ máàjẹ́-ò-bàjẹ́ tí ẹgbẹ́-òṣèlú alátakò All Nigeria Peoples Party, ní Nigeria. Aikhomu ṣe ìrànlọ́wọ́ ìwòsàn àrùn ibà-lásà, lassa fever ní ilé-ìwòsàn, Irrua Specialist Hospital.[2] Ó kú ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2011. Aya àti ọmọ márùn-ún tí ẹbí ló gbẹ̀yìn rẹ̀.
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.