From Wikipedia, the free encyclopedia
AbdulRahman AbdulRazaq (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1960) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà, ẹni tí ó jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara láti ọdun 2019.[1] Òun ni alága télèrí ilé-isé First Fuels Limited.[2] Ó dupò gómìnà ìpínlè Ìpínlẹ̀ Kwara ní 2003, 2007 àti 2011 lábé ẹgbẹ́ òsèlú Congress for Progressive Change ṣùgbọ́n ó fìdí rẹmi, Abubakar Bukola Saraki dé ipò náà ní ọdun 2003 àti 2007, tí Abdulfatah Ahmed sì dé ipò náà ní 2011.[3] Ní ọdun 2019, ó dupò náà lẹ́kan si lábé ẹgbẹ́ òsèlú tí ó wá ìjọba, ẹgbẹ́ òsèlú All Progressive Congress, ó sì jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bi gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara.[4] Ní 2021, ó dá KwaraLEARN kalẹ̀ ní ilé ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ láti ran àwọn ògá lọ́wọ́ nínú kíkó àwọn akẹ́kọ̀ọ́.[5]
Abdulrahman Abdulrazaq | |
---|---|
Governor of Kwara State | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 29 May 2019 | |
Deputy | Kayode Alabi |
Asíwájú | Abdulfatah Ahmed |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Kejì 1960 Zaria, Northern Region, British Nigeria (now in Kaduna State, Nigeria) |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress (APC) |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Olufolake Davies AbdulRazaq |
Website | "Abdulrahman AbdulRazaq" |
A bí AbdulRahman ní Ilorin West Local Government.[3] Òun nìkan ni ọmọ ọkùnrin Alhaji A. G. F. AbdulRazaq SAN., agbejọ́rò àkókò ní àríwá Nàìjíríà[6]
Ó lọ ilé-ìwé Capital School, ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàrin 1966 and 1968; ó tún lọ ilé-ìwé Bishop Smith Memorial School Ilorin láàrin ọdún 1970 àti 1971; àti Government College Kaduna níbi tí ó ti gba ìwé ẹrí West African Senior School Certificate Examination (WASSCE) rẹ̀ ní ọdún 1976.[3][7]
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú òsèlú ní ọdún 1999 nígbà tí Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa n tiwa. Ní ọdún 2003 àti 2007, ó dupò Gómìnà ìpínlè Kwara lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Congress Progressive Change(CPC) ṣùgbọ́n ó fìdí remi[8] ó tún dupò náà lábé ẹgbẹ́ òsèlú People Democratic Party (PDP) ní ọdún 2011 àti 2015.[9] Ó jáwẹ́ olúborí nígbà tí ó dupò náà ní ẹ̀kan si lábé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress ni ọdún 2019.[10][8]
Ó búra wọlé sí ipò Gómìnà ìpínlè Kwara ní ọjọ́ kandínlọ́gbọ̀n oṣù Kàrún ọdún 2019.[11]
Ìyàwó AbdulRahman ni Olufolake Molawa Davies Abdulrazaq[3] àwọn méjèèjì sì ní ọmọ mẹ́ta.[12]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.