Ìjọba Ìbílẹ̀
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìjọba Ìbílẹ̀ jẹ́ ìpele ìjọba ẹlẹ́kẹta àti irúfẹ́ ìjọba tí ó jẹ́ ti àwa-ara-wa lẹ́sẹ̀ kùkú ti ó wà ní abẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lábẹ́ ìlànà ìṣèlú àwa-ara-wa.[1] Ìjọba ìbílẹ̀ ma ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin àti àlàkalẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè bí àwọn aṣòfin (legistlatives) àti àwọn amòfin (Judiciary) ṣe gbe kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà étò Ìjọba Àpapọ̀ (Federal State), ìjọba ìbílẹ̀ ló sába ma ń wà ní ipò kẹta nínú étò ìṣèlú. [2]
Ẹ̀wẹ̀ àgbékalẹ̀ étò Ìjọba ìbílẹ̀ yàtọ̀ síra wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní agbáyé. [3]