![cover image](https://wikiwandv2-19431.kxcdn.com/_next/image?url=https://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/f/fe/Ortho_tricyclen.jpg/640px-Ortho_tricyclen.jpg&w=640&q=50)
Ìfètò sọ́mọ bíbí
From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìfètò sọ́mọ bíbí ni a lè pe ní ìlànà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ní ṣe pẹ̀lú bí a ṣe lè pinu lórí iye ọmọ tí ó bá wuni láti bí, láì kò sí ìjẹni nípa lórí bí a ṣe lè fi àsìkò sí àárín àwọn ọmọ tí a fẹ́ bí náà lọ́nà tí kò ní pa wá lára, yálà ní Oògùn lílò, ìgbé ayé tí ó dára nínú àwùjọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ .[1] Ètò ìlànà ìfètò sọ́ọ́mọ bíbí tún dá lórí pípinu lórí bóyá kí obìnrin ó me iye ọmọ tí ó bá fẹ́ bí kí ó sì fi àsìkò sí àárín wọn, tàbí kí ó pinu lá má tilẹ̀ dábàá àti bímọ kankan rárá láyé rẹ̀, tàbí kí ó fi aye sílẹ̀ fún ọmọ bíbí nínú ònkà ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó fẹ́ fi bímọ. Àwọn ìpinu tí a ká sókè yí ni àyípadà ma ń dé bá látàrí àwọn kókó bí :
- àìlówó lọ́wọ́
- uṣẹ́ òòjọ́ obìnrin (career),
- ipo Ìgbéyàwó
- àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí ó lè mú kí lọ́kọ-láyà ó má lè rọ́mọ bí nínú Ìgbéyàwó wọn, tàbí kí wọ́n má lè tọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí.
![Thumb image](http://upload.wikimedia.org/wikipedia/commons/thumb/f/fe/Ortho_tricyclen.jpg/640px-Ortho_tricyclen.jpg)