From Wikipedia, the free encyclopedia
Oríṣìíríṣìí àwọn onímọ̀ ní ó ti gbìnyànjú láti fún èdè ní oríkì kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oríkì wònyìí, kíni èdè túmọ̀ sí?
Èdè níí ṣe pẹ̀lú ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń lò ní àwùjọ yálà fún ìpolówó ọjà, ìbáraẹni sọ̀rọ̀ ojoojúmó, ètò ìdílé tàbí mọ̀lẹ́bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [1] Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ó ní: Èdè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìrú kan gbòógì tí àwùjọ àwọn ènìyàn ń lò láti fi bá ara ẹni sọ̀rọ̀. Raji (1993:2) pàápàá ṣe àgbékalẹ̀ oríkì èdè ó ṣàlàyé wípé; “Èdè ni ariwo tí ń ti ẹnu ènìyàn jáde tó ní ìlànà. Ìkíní lè ní ìtumọ̀ kí èkeji maa ní. Èdè máa ń yàtọ̀ láti ibìkan sí òmíràn. Ohun tó fà á ni pé èdè kọ̀ọ̀kan ló ní ìwọ̀nba ìrú tó ń mú lò. Èdè kankan ló sì ní ìlànà tirẹ̀ to ń tèlé.” Wardlaugh sọ nínú Ogusiji et al (2001:10) wí pé: “Èdè ni ni àwọn àmì ìsọgbà tí ó ní ìtumọ̀ tí o yàtọ̀ tí àwọn ènìyàn ń lò láti fi bá ara wọn sọ̀ọ̀.” Àwọn Oríkì yìí àti ọ̀pọ̀lọpọ oríkì mìíràn ni àwọn Onímọ̀ ti gbìyànju láti fún èdè, kí a tó lè pe nǹkan ní èdè, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn èròja wọ̀nyí: èdè gbọ́dọ̀ jẹ́:
1. Ohun tí a lè fi gbé ìrònú wa jáde
2. Ariwo tí ó ń ti ẹnu ènìyàn jáde
3. Ariwo yìí gbọ́dọ̀ ní ìtumọ̀
4. Aríwo yìí gbọ́dọ̀ ní ìlànà ìlò tí yóò ní bí a ti ṣe ń lò ó.
5. Kókó ni á ń kó ọ, kì í ṣe àmútọ̀runwá
6. nǹkan elémú-ín tó lè dàgbà sí i, tó sì lè kú ikú àìtọ́jọ́ ni èdè.
7. A lè so èdè lẹ́nu, a sì le kọ́ sìlè.
Síwájú sí í, a ní àwọn àbùdá ti èdè ènìyàn gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ
(1) Ìdóhùa yàtọ̀ sí ìtumọ̀ (Ar’bitransess)
(2) Àtagbà Àṣà (Cultural transmission)
(3) Agbára Ìbísí (Productivity) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lo. Gbogbo Ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀[2] mìíràn yàtọ̀ láàrín èdè ènìyàn àti ti ẹranko kì í ṣe ohun tí ó rorùn rárá. Nǹkan àkọ́kọ́ nip é a gbọ́dọ̀ wá oríkì èdè tó ń ṣiṣé lórí èyí tí a ó gbé ìpìnlè àfiwé wa lè. Ṣùgbọ́n ṣá, kò sí oríkì tí ó dàbí ẹni pé ó ṣàlàyé oríkì èdè tàbí tí ó jẹ́ ìtéwógbà fún gbogbo ènìyàn. Charles hocket ṣe àlàyé nínú Nick Cipollone eds 1994 wípé: Ọ̀nà kan gbòógì tí a fi lè borí ìṣòro yìí nip é, kí a gbìnyànjú láti ṣe ìdámọ̀ ìtúpalẹ̀ àwọn àbùdá èdè ju kí a máa gbìnyànjú láti fún ẹ̀dá rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì ní oríkì. Torí náà, a lè pinu bóyá èdè ẹranko pàápàá ni àwọn abida yìí pẹ̀lú… Ohun tí a mọ̀ nípa èdè ẹranko ni pé, kò só èdè ẹranko kọ̀ọ̀kan tí ó ní àwọn àbùdá èdè ènìyàn tí a ti sọ síwájú. Èyí ni ó mú kí á fẹnukò wípé àwọn èdà tí kìí ṣe àwọn ènìyàn kì í lo èdè. Dípò èdè, wọn a máa bá ara wịn sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ń pè ní ẹ̀nà, àpẹẹrẹ ìfiyèsí (Signal Cocle). Gbogbo ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn yàtọ̀ sí èyí kì í ṣe èdè. Àwọn ọ̀nà náà ní:
(1) Ìfé sísú
(2) Ojú ṣíṣẹ́
(3) Èjìká sísọ
(4) Igbe ọmọdé
(5) Imú yínyín
(6) Kíkùn ẹlẹ́dẹ̀
(7) Bíbú ti kìnnìún bú
(8) Gbígbó tí ájá ń gbó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gbogbo ariwo ti a kà sílẹ̀ wọ̀nyí kì í ṣe èdè nítorí pé;
(1) Wọ́n kò ṣe é fọ́ sí wẹ́wẹ́
(2) Wọn kì í yí padà
(3) Wọn kì í sì í ní Ìtumọ̀
Pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti sọ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàrín èdè ènìyàn àti ẹranko, Ó hàn gbangba wípé a kò le è fi èdè ẹranko àti ti ènìyàn wé ara wọn. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “igi ímú jìnnà sí ojú, bẹ́ẹ̀ a kò le è fi ikú wé oorun. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èdè ènìyàn àti ẹranko rí. Nínú èdè ènìyàn lati rí gbólóhùn tí ènìyàn sọ jáde, tí a sì le è fi ìmò ẹ̀dá èdè fọ́ sí wẹ́wẹ́. Àtiwípé àǹfàní káfi èdè lu èdè kò sí ní àwùjọ ẹranko gẹ́gẹ́ bí i ti ènìyàn. Bí àpẹẹrẹ. Olú ra ìṣu Olú nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò Olùwá, rà jẹ́ Ọ̀rọ̀-ìṣe nígbà tí ísu jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ ní ipò ààbọ̀. A kò le rí àpẹẹrẹ yìí nínú gbígbó ajá, kike ẹyẹ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà èdè ènìyàn yàtọ̀ sí enà apẹẹrẹ, ìfiyèsí (Siganl Code) àwọn ẹranko.
Fatusin, S.A (2001), An Introduction to the Phonetics and Phonology of English. Green-Field Publishers, Lagos.
Rájí, S.M (1993), Ìtúpalẹ̀ èdè àṣà lítíréṣọ̀ Yorùbá. Fountan Publications, Ibadan.
Ogunsiji, A and Akinpẹlu O (2001), Reading in English Languag and Communication Skills. Immaculate-City Publishers, Oyo.
Nic Cipollone eds (1998), Language files Ohio State University Press, Columbus.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.