Èdè Arméníà
From Wikipedia, the free encyclopedia
From Wikipedia, the free encyclopedia
Èdè Arméníà jẹ́ ọ̀kan lára èdè Indo-European (Indo-Ùrópóàànù) kan ni eléyìí. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíònù méje. Àwọn tí ó ń sọ ọ́ ní orílẹ̀-èdè Armenia jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (3.6 million). Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Turkish Armenia. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní Europe (Úróòpù), Àmẹ́ríkà (USA) àti ààrin gbungbun ìlà-oòrùn àgbáyé (Middle East) náà ń sọ èdè náà.
Armenian | |
---|---|
Հայերեն Hayeren | |
Sísọ ní | Armenia, Russia, Iran, France, Lebanon, Syria, Georgia, Canada, United States Nagorno-Karabakh (not recognized internationally) |
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀ | 6.7 million [1] |
Èdè ìbátan | Indo-European
|
Sístẹ́mù ìkọ | Armenian alphabet |
Lílò bíi oníbiṣẹ́ | |
Èdè oníbiṣẹ́ ní | Armenia Nagorno-Karabakh Republic (internationally unrecognised) Minority language:[2] Àdàkọ:CYP |
Àkóso lọ́wọ́ | National Academy of Sciences of Armenia |
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè | |
ISO 639-1 | hy |
ISO 639-2 | arm (B) hye (T) |
ISO 639-3 | variously: hye – Modern Armenian xcl – Classical Armenian axm – Middle Armenian |
Èdè Armenia àtijọ́ (Classical Armenian tí wọ́n ń pè ní Grabar ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ lítíréṣọ̀ sílẹ̀ ní gbogbo àgbáyé. Wọ́n kọ ọ́ ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì karùn-ún lẹ́yìn ikú Jésù Kírísítì Èdè Grabar yìí ni wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí èdè ẹ̀sìn fún àwọn ijọ ilẹ̀ Armenia òde òní,
Lẹ́tà álúfábẹ́ẹ̀tì méjìdínlógòjì ni wọ́n fi ń kọ èdè yìí sílẹ̀. St Mesrop ni ó ṣẹ̀dá álúfábẹ́ẹ̀tì yìí.
Oríṣìí méjì ni ẹ̀yà èdè yìí ni ayé òde òní. Ọ̀kan nit i apá Ìlà oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní, ìpínlẹ̀ Yeravan. Òun ni wọ́n ń lò ní orílẹ̀-èdè Armenia. Èkejì nit i Ìwọ̀-oòrùn tí wọ́n gbé lé orí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ ní Islanbul. Eléyìí ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Turkey.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.