Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America From Wikipedia, the free encyclopedia
Laurence John Fishburne III[1] (tí a bí ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù keje ọdún 1961) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ Emmy Award ní ẹ̀mẹ́ta tí àti àmì ẹyẹ Tony Award. Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Morpheus nínú The Matrix series (1999–2003), Jason "Furious" Styles nínú eré John Singletontí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Boyz n the Hood (1991), Tyrone "Mr. Clean" Miller nínú eré Francis Ford Coppola tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Apocalypse Now (1979), àti gẹ́gẹ́ bi "The Bowery King" nínú John Wick film series (2017–títí I di ìsinsìnyí).
Fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Ike Turner nínú What's Love Got to Do With It (1993), Fishburne wà lára àwọn tí wọ́n yàn pé ó tó sí àmì ẹyẹ Academy Award for Best Actor. Ó tún gba àmì-ẹ̀yẹ Tony Award for Best Featured Actor in a Play fún ipa rẹ̀ nínú Two Trains Running (1992), àti Emmy Award for Outstanding Guest Actor in a Drama Series fún ipa rẹ̀ ní TriBeCa (1993).
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.