From Wikipedia, the free encyclopedia
Ira Frederick Aldridge (tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1807, tí ó sì di olóògbé ní ọjọ́ keje oṣù kejọ, ọdún1867) jẹ́ òṣèrékùnrin àti adarí eré orí-ìtàgé tó wá láti orílẹ̀-èdè American. Ó di ìlú-mọ̀ọ́-ká látàrí fífi ẹ̀dá-ìtàn Shakespeate hàn. James Hewlett àti Aldridge ni a lè pè ní àwọn aláwọ̀-dúdú àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń ṣe eré apanilẹ́kún.
Ira Aldridge | |
---|---|
Portrait of Aldridge by James Northcote, 1826 | |
Ọjọ́ìbí | New York City, United States | Oṣù Keje 24, 1807
Aláìsí | August 7, 1867 ọdún 60) Łódź, Poland | (ọmọ
Burial place | Old Łódź Cemetery, Poland |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | United States, United Kingdom |
Iṣẹ́ | Actor, playwright |
Ìgbà iṣẹ́ | 1820s–1867 |
Olólùfẹ́ | Margaret Gill, Amanda von Brandt |
Àwọn ọmọ | Ira Daniel, Amanda, Ira Frederick, Luranah, Rachael |
Ìlú New York City ní wọ́n bí Aldridge sí, sínú ìdílé ìránṣẹ́ Ọlọ́run Daniel àti Luranah, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1807. Àmọ́ àwọn ìwé kan sọ pé wọ́n bi sí Bel Air, Maryland.[1]
Iṣẹ́ Aldridge àkọ́kọ́ wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún 1820 pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Afirika kan, èyí tí William Henry Brown àti James Hewlett ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.[2][3]
Ní oṣù karùn-ún, ọdún 1825, nígbà tí ó pé ọmọdún mẹ́tàdínlógún, Aldridge ṣe ìfarahàn àkọ́kọ́ rẹ̀ sí ìlú London lásìkò tí wọ́n fẹ́ ṣe àgbéjáde fíìmùOthello.[4] Ní oṣù kẹwàá ọdún 1825 bákan náà, Aldridge tún ṣiṣẹ́ gọbọi mìíràn ní London Royal Coburg Theatre, ó sì di aláwọ̀-dúdú àkọ́kọ́ tí á ṣe ìdásílẹ̀ ara rẹ̀ ní ilẹ̀ àjèjì. Ó ṣe Oroonoko nínú fíìmù The Revolt of Surinam, or A Slave's Revenge.[3]
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.