From Wikipedia, the free encyclopedia
Immanuel Kant (Pípè nì Jẹ́mánì: [ɪˈmaːnu̯eːl ˈkant]) (22 April 1724 – 12 February 1804) je amoye ara Jemani ti orundun 18th lati ilu Königsberg ni Prussia. Kant lo je amoye gbeyin tonipa ni Europe odeoni ninu afinuro imo nigba Olaju to bere pelu awon alayan bi John Locke, George Berkeley, ati David Hume.[1]
Immanuel Kant | |
---|---|
Immanuel Kant | |
Orúkọ | Immanuel Kant |
Ìbí | 22 Oṣù Kẹrin 1724 Königsberg, Prussia |
Aláìsí | 12 February 1804 ọdún 79) Königsberg, Prussia | (ọmọ
Ìgbà | Ìmòye ọ̀rúndún 18th |
Agbègbè | Ìmòye Apáìwọòrùn |
Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ | Isekantiani, imoye olaju |
Ìjẹlógún gangan | Oro-ijinle, Oro=adanida, Iwawiwu, Ogbon |
Àròwá pàtàkì | Categorical imperative, Transcendental Idealism, Synthetic a priori, Noumenon, Sapere aude, Nebular hypothesis |
Ìpa lórí
| |
Ìtọwọ́bọ̀wé |
Kant seda ona igbewo tuntun ninu imoye to ni ipa kakiri lori imoye kakiri orundun 21st. O satejade awon ise pataki lori oro-ijinle, lori esin, ofin, ati itan. Ikan ninu iwe re pataki ni Agbeyewo Ironu Sasa, to je iwadi lori opin ati opo ironu fun ra re gan. O gbogun ti awon iru oro-adanida ati oro-ijinle to wa tele, o si falasi afikun Kant gan si awon eyi. Awon ise miran to tun se bi agbalagba ni Agbeyewo Ironu Alagbese, to dawo lori iwawiwu, ati Agbeyewo Idajo, to sewadi which investigates oro-ewa ati iwadopin.
Kant damoran pe oro-adanida se tunse pelu oro-ijinle.[2] O so pe nipa liloye awon orisun ati awon opin imo omo-eniyan a le bere awon ibere oloro-ijinle ti yio ni eso. O bere boya ohun kan le je mimo pe o ni awon ini pato kan ki o to di pe iriri ohun na waye. O pinu pe gbogbo awon ohun ti emi le ro nipa won gbodo je bi iru ero re. Nipa bayi ti emi ba le ro lasan nikan bi titori (causality) – ti Kant gba pe o je be – nigbana a le mo won ki a to ni iriri won pe gbogbo awon ohun ti a ni iriri won gbodo je itori tabi ìṣẹlẹ̀. Sibe, o je bayi pe o se e se pe awon ohun kan wa ti eda won ko se fi emi ro, nitorie opo titori, fun apere ko se mulo laisi iriri: o je be pe a ko le mo, fun apere, boya ile-aye ti wa lailai tabi boya ohun kan lo fa wa. Bi be awon ibere ninla oro-ijinle alafinuro ko l ni idahun pelu emi omo-eniyan, sugbon sayensi fidimule sansan ninu awon ofin emi.[3] Iwadi lri idimule ati idagba opolo ninu awon eranko satileyin ironusi Kant, botileje fun ifuramo aaye; eyun, isoju aaye ayika lamupo ohun kan to siwaju ifuramo gangan ayika na fun ra re.[4][5][6]
Kant gbagbo pe ohun unda ilaja laarin awon oluseiriri ati awon oluselaakaye. Awon oluseiriri gbagbo pe imo unwa latinu iriri nikan, sugbon awon oluselaakaye tenumo pe imo le bo si abe iyemeji Kartesi ati pe ironu nikan lo le fun wa ni imo. Sugbon ijiyan Kant nipe, lilo ironu lai mulo mo iriri yio fa itanraenije wa, nigba ti iriri yio je tonitoun ti a ko ba koko fi ironu saka wo.
Ero Kant nipa ni Jermani igba aye re, nipa mimu imoye losiwaju ijiyan larin awon oluselaakaye ati oluseiriri. Awon amoye Fichte, Schelling, Hegel ati Schopenhauer ri ara won bi eni to satunse ati samufe sistemu Kantiani, bi be won samuwa orisi iru Isearowa ti Jermani. Titi doni Kant unnipa pataki lori imoye, nipa ipa re lori imoye alatuwo ati imoye orile Europe.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.