Whitney Houston
Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America / From Wikipedia, the free encyclopedia
Whitney Elizabeth Houston (August 9, 1963 – February 11, 2012) jẹ́ akorin, òṣèré, olóòtú eré, àti ẹlẹ́yinjú-àánú ará Amẹ́ríkà. Arábìnrin yìí tí ìnagijẹ rẹ̀ jẹ́ "Ohùn Náà", jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òṣèré orin gbogbo ìgbà tí ó gbajúgbajà jùlọ, lẹ́yìn tí ó fojú hànde nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìgbajúgbajà. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fojú hànde lórí àtẹ òrin tó gbajúgbajà, àti pé àwọn ìkópa rẹ̀ kópa nínú ìbẹ́níṣòó ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti àṣà tó gbajúgbajà.[1][2] [3]
Whitney Houston | |
---|---|
Houston at the Welcome Home Heroes concert in 1991 | |
Ọjọ́ìbí | Whitney Elizabeth Houston (1963-08-09)Oṣù Kẹjọ 9, 1963 Newark, New Jersey, U.S. |
Aláìsí | February 11, 2012(2012-02-11) (ọmọ ọdún 48) Beverly Hills, California, U.S. |
Burial place | Fairview Cemetery, Àdàkọ:Avoid wrap |
Ẹ̀kọ́ | Mount Saint Dominic Academy |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1977–2012 |
Olólùfẹ́ | Bobby Brown (m. 1992; div. 2007) |
Àwọn ọmọ | Bobbi Kristina Brown |
Parent(s) |
|
Àwọn olùbátan |
|
Awards |
|
Website | whitneyhouston.com |
Musical career | |
Irú orin | |
Labels |
|
Signature | |
Houston gbajúgbajà fún ìgbólohùn rẹ̀, ìdáyàtọ̀ rẹ̀, àtí mímú kí ìlò ọ̀nà orin ẹ̀mí láti fi kọ orin tàkasúfèe.[4][5] Ní ọdún 2023, ilé-iṣẹ Rolling Stone ṣe àfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni kejì lórí àtò àwọn olórin olókìkì ìgbàdégbà. Houston ti ta okòólénígba mílíọ̀nù àwo-orin káàkiri àgbáyé, léyìí tó mú un jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tó tà jù lágbàáyé, nínú ìtàn. Ó tún rí òkìkí rẹ̀ nípa ṣíṣe olóòtú àti kíkópa nínú àwọn eré àgbéléwò ajẹmọ́-oríṣiríṣi-àṣà. Ìgbéayé àti iṣẹ́ rẹ̀ ti jẹ ohun àmẹ́nubà fún ìkótànjọ àti ìmẹ́nubà lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Houston bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ní New Hope Baptist Church ní Newark, New Jersey, gẹ́gẹ́ bí i ọmọdé, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ń kọrin ní ilé-ìwé rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti farahàn nínú orin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Seventeen, lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣé módẹ́ẹ̀lì ní ọdún 1981. Pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà alága Arista Records, ìyẹn Clive Davis, Houston tẹwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ náà ní ọmọdún mọ́kàndínlógún (19). Àwọn orin àkọ́kọ́ rẹ̀ ni Whitney Houston (1985) àti Whitney (1987), tí ó sì tà gan-an lọdún náà.