From Wikipedia, the free encyclopedia
Ìdíje French Open(Ṣíṣí Faransé) (Faransé: Internationaux de France de Tennis), tí a tún mọ̀ sí Roland-Garros (Faransé: [ʁɔlɑ̃ ɡaʁos]), jẹ́ gbajúgbajà ìdíje bọ́ọ̀lù Orí pápá Alámọ̀ tennis tournament tí ó máa ń wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ méjì ní pápá ìṣeré Stade Roland-Garros Ní ìpínlẹ̀ Paris, ní orílẹ̀-èdè Faransé, ní òpin oṣù karùn-ún ọdọọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdíje náà máa ń wáyé gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ láàrin oṣù karùn-ún sí oṣù kẹfà, àwọn ìgbà kan wà tí kò wáyé ní ìgbà náà fún àwọn ìdí bí í:
Ìdíje yìí àti pápá ìṣeré rẹ̀ ni wọ́n fi sọrí Roland Garros tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ọkọ̀ òfurufú. Ìdíje French Open jẹ́ gbóògì láàrin àwọn ìdíje orí pápá Alámọ̀ lágbàáyé. Òun ni ó ṣe ipò Kejì nínú mẹ́rin tí ó jẹ́ pàtàkì bíi irú rẹ̀. Àwọn mẹ́ta yòókù ni ìdíje Australian Open, Wimbledon, atì Ìdíje US Open. Ìdíje French Open nìkan ni ìdíje pàtàkì tí wọ́n ń ṣe ni orí Amọ̀. Títí di ọdún 1975, ìdíje yìí nìkan ni wọn ò tíì ma gbá ní Orí pápá oníkoríko. Nínú àláálẹ̀ méjèèje tí wọ́n fi ń mọ ìdíje tí ó yanrantí, ìdíje French Open yìí ni wón lérò pé ó gba agbára jùlọ.
Seamless Wikipedia browsing. On steroids.
Every time you click a link to Wikipedia, Wiktionary or Wikiquote in your browser's search results, it will show the modern Wikiwand interface.
Wikiwand extension is a five stars, simple, with minimum permission required to keep your browsing private, safe and transparent.