Nelson Mandela
From Wikipedia, the free encyclopedia
Nelson Rolihlahla Mandela (IPA: [xoˈliɬaɬa manˈdeːla]; Ọjọ́ Kejìdínlógún Oṣù Keje Ọdún 1918 - Ọjọ́ Karùn-ún Oṣù Kejìlá Ọdún 2013)[1][2] jẹ́ Ààrẹ Gúúsù Áfíríkà láti ọdún 1994 títí di ọdún 1999, bẹ́ẹ̀ sì ni òun ni Ààrẹ Gúúsù Áfírík[s àkọ́kọ́ tó jẹ́ ẹni àdìbòyàn nínú ìdìbò-yani tòṣèlú ará ìlú aṣojú yanyan. Kí ó tó di Ààrẹ, Mandela jẹ́ alákitiyan olódì-apartheid, ati olórí Umkhonto we Sizwe, apa adigun Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Áfíríkà (ANC). Lọ́dún 1962 ó di ẹni afofinmu won si da lebi ika ote ati awon ẹ̀sùn mìíràn, wọ́n sì rán an lẹ́wọ̀n gbere. Mandela lo ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ní ẹ̀wọ̀n, ó lo ọ̀pọ̀ ọdún yìí ní Robben Island. Lẹ́yìn jijowo rẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní ọjọ́ 11 oṣù kejì ọdún 1990. Mandela ṣiwájú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ nínú àwọn iforojomitorooro tó fa òṣèlú àwaarawa ti gbogbo eya ti o waye ni odun 1994, tó sì di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Gúúsù Áfíríkà láti ọdún 1994 títí di 1999. O si ṣokùnfà ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní Gúúsù Afrika, Bákan náà ni a tún mọ Mandela sí Madiba, oyè ẹ̀yẹ tí àwọn Alágbà ìdílé Mandela ń lo.
Ẹni ọ̀wọ̀ Nelson Mandela | |
---|---|
Mandela in 2008 | |
Ààrẹ ilẹ̀ Gúúsù Áfríkà | |
In office 10 May 1994 – 14 June 1999 | |
Deputy | Thabo Mbeki Frederik Willem de Klerk |
Asíwájú | Frederik Willem de Klerk Bi State President of South Africa |
Arọ́pò | Thabo Mbeki |
Secretary General of Non-Aligned Movement | |
In office 3 September 1998 – 14 June 1999 | |
Asíwájú | Andrés Pastrana Arango |
Arọ́pò | Thabo Mbeki |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Rolihlahla Mandela (1918-07-18)18 Oṣù Keje 1918 Mvezo, Union of South Africa |
Aláìsí | 5 December 2013(2013-12-05) (ọmọ ọdún 95) Johannesburg, Gúúsù Áfríkà |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Gúúsù Áfríkà |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | African National Congress |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Evelyn Ntoko Mase (1944–1957) Winnie Madikizela (1957–1996) Graça Machel (1998–present) |
Residence | Houghton Estate, Gúúsù Áfríkà |
Alma mater | University of Fort Hare University of London External System University of South Africa University of the Witwatersrand |
Signature | |
Website | Mandela Foundation |
Mandela ti gba ẹ̀bùn tó pọ̀ ju 250 lọ láàárín ogójì ọdún, nínú wọn ni Ẹ̀bùn Àlàáfíà Nobel 1993.